Rachel Oniga is dead: Jide Kosoko, Hilda Dokubo, Yomi Fabiyi àtàwọn míì ṣèdárò Rachel Oniga tó lọ

Jide Kosoko Rachel Oniga

Oríṣun àwòrán, Others

Ọpọ awọn osere ati ololufẹ ogbontarigi oṣere ni Rachel Oniga to jade laye lana ni wọn ti n kira wọn ku ara feraku.

Rachel Oniga to dagbere faye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta.Mi kò mọ̀ pé àsìkò yìí ni máa dágbéré fún Rachel Oniga- Jide Kosoko

Jide Kosoko, agba ọjẹ osere naa ti sọrọ sita pe iku Oniga ṣe oun fuu.

O ni oun ko mọ pe ọrẹ bii ọmọ iya yii n dagbere lasiko yii fun oun ni.

Oríṣun àwòrán, @Jide Kosoko

Jide Kosoko ni nitootọ ni iku Rachel Oniga dun oun ṣugbọn oloogbe gbe igbeaye to wuni lori pupọ.

O dagbere fun oloogbe to ni o kọja akégbẹ ẹni lẹnu iṣẹ lasan pẹlu ileri pe gbogbo oṣere ni yoo maa ṣranti iṣẹ rere ati ohun maleegbagbe ti akinkanju obinrin yii, Rachel Oniga se silẹ lagbo tiata ko to lọ.

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Oríṣun àwòrán, racheloniga

Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Rachel Oniga tó d'ágbére f'áyé

Ìtàn ìgbéayé gbajúgbajà òṣèré, Rachel Oniga tó jáde láyé rèé

Gbajugbaja oṣere tiata, Rachel Oniga ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta.

Àkọlé fídíò,

Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria, Actor's Guild of Nigeria, Emeka Rollas lo fidi iroyin naa mulẹ pe pe lootọ ni oṣerebinrin naa ti jẹ Ọlọrun nipe.

Rolla ni ọmọ oloogbe ọhun sọ fun oun pe oṣerebirin naa dagbere faye ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọgbọn ọjọ, oṣu Keje, ọdun 2021 yii.

Ṣugbọn o fi kun pe oun ko tii le ṣalaye ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa.

Wo awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Rachel Oniga

  • Ọmọ bibi ilu Eku, nipinlẹ Delta ni Rachel Oniga
  • Wọn bi i ni ipinlẹ Eko ninu oṣu Karun un, ọdun 1957, lagbegbe Ebute Metta
  • O kawe nile ẹkọ Princess Girls School, to wa ni Abule Oja, Yaba, niluu Eko
Àkọlé fídíò,

Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

  • Ọlọrun fi ọmọ mẹta ta Rachel lọrẹ ṣugbọn oun ati ọkọ rẹ ko gbe papọ mọ ki ọlọjọ to de
  • Awọn eniyan to sọrọ nipa iku rẹ ni o ṣi kopa ninu fiimu ti wọn n ṣe lọwọ ni ọṣẹ yii, ni agbegbe Mowe, nipinlẹ Ogun
  • Racheal Oniga wa lati ilu Eku ni ipinlẹ Delta, amọ agbegbe Ebutte Metta ni ipinlẹ Eko ni wọn bi sii.
Àkọlé fídíò,

Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

  • O bẹrẹ iṣe ẹ oṣere rẹ ni ọdun 1993, kete to fi igbeyawo rẹ silẹ ni nkan bi ọdun mọkandinlogun sẹyin.
  • Ki o to bẹrẹ iṣẹ oṣere, o kọkọ ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Ascoline Nigeria Limited.
  • Fiimu akọkọ ti o kọkọ kopa ninu rẹ ni Onome ati fiimu Yoruba Owo Blow.
  • Awọn fiimu miran to ti kopa ninu rẹ ni Sango, Super Story, "Died Wretched," "The Only Nigerian Girl," "Doctor Bello" ,"The Royal Hotel Hibiscus."The Wedding Party, The Royal Hibiscus Hotel, 30 Days in Atlanta, ati Out of Bounds,
Àkọlé fídíò,

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.

Pupọ ninu awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ.

Lara awọn oṣere naa ni Jide Kosoko to sọ pe oun ṣi ranti gbogbo igba ti awọn mejeji jọ maa n kopa ninu ere bi ana.

O ni Rachel Oniga kii ṣe akẹgbẹ oun nikan, ṣugbọn o tun jẹ bii ibatan si oun.

Àkọlé fídíò,

Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

Ni ti Hilda Dokubo, o ni bii iya ni Rachel Oniga jẹ si oun, eyii to mu ki iku rẹ jẹ ọgbẹ ọkan fun oun.

Bakan naa ni Yomi Fabiyi n ṣedaro oloogbe naa nigab to sọ pe awọn memeji ṣi fọrọ jomitooro ọrọ ni ọjọp mẹfa sẹyin.

Yatọ si awọn oṣere tiata, pupọ awọn ololufẹ Rachel Oniga lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajúgbajà òṣèré, Racheal Oniga ti d'ágbére f'áyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Igbo ati ede Gẹẹsi, Rachael Oniga ti jẹ Ọlọrun nipe.

Eni ọdun mẹrinlelọgọta ni Oniga ko to jade laye.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria, Actor's Guild of Nigeria, Emeka Rollas ni lootọ ni oṣerebinrin naa ti jade laye.

Rollas sọ fun BBC pe akọwe oun pe ọmọ Racheal Oniga to fi idi rẹ mulẹ wi pe alẹ Ọgbọnjọ, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni iya oun jade laye.

Titi di asiko yii, ko i tii si aridaju ohun to ṣokunfa iku rẹ.