Micheal Usifo Ataga: Ìyá, ìyàwó sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa olóògbé níbí ìsìnkú

Michael Usifo Ataga

Oríṣun àwòrán, Others

Iya oloogbe adari ileeṣẹ Super TV, Michael Usifo Ataga ti sọ iwuri nipa ọmọ rẹ gẹgẹ bi alaanu to ni ifẹ oun ati awọn eniyan to sun mọ rẹ.

Iya ologbe naa sọ ọrọ yii nibi isinku ti ẹbi ati ara pesi lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun ni Ebony Vaults, ni Ikoyi, nipinlẹ Eko

Bonkẹlẹ ni wọn ṣe ẹyẹ ikẹyin naa fun ọjọ meji, to si jẹ awọn ẹbi ati ara nikan ni wọn pe si ẹyẹ ikẹyin.

Ọjọbo ni wọn ṣe aṣalẹ orin fun oloogbe naa, nibi ti awọn ẹbi ati ara ti sọ ọrọ iwuri nipa ọmọ rẹ.

Iya rẹ, Slyvia Ataga ni ọmọ oun ku iku ti ko tọsi nitori ko t si ọmọ oun iru nkan ti wọn ṣe fun.

''Ọkan mi gbọgbẹ nipa iku ọmọ mi nitori eniyan ire ni to ni aanu, ti ko si si ẹni ti kii ṣe aanu fun.''

Oríṣun àwòrán, Others

Bakan naa iyawo rẹ, Brenda Ataga ninu ọrọ rẹ ni iroyin iku ọkọ oun ba oun ni inu jẹ gidigidi nitori kii ṣe iru iroyin ti oun ro si niyẹn.

'' Gbogbo ero lo wa si mi lọkan, amọ kii ṣe ti iku rara, ati pe nibo lo le wa, abi ki lo ṣẹlẹ, amọ iroyin iku kọ ni mo fẹ.''

Oríṣun àwòrán, Others

''Ati pese gbogbo ohun ti yoo ṣe moriya fun ọ lọjọ ayajọ ọjọ ibi rẹ, ki o kan wọle, ki a si ṣe ẹyẹ fun ọ, lo di nkan ti a ko le ri ọ mọ.''

Ọjọ Kẹrinlelogun, Oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣafihan oju Chidinma nigba to jẹwọ pe oun lo n gun Ataga ẹni aadọta ọdun naa lọbẹ lọrun pa lẹyin gbọnmi sii omi o to.

Oríṣun àwòrán, Others

Ki ileeṣẹ ọlọpaa to gbe iroyin naa jade ni awọn ọrẹ Ataga fi lede wi pe wọn n wa Ataga to n gbe Banana Island lati Ọjọ Kẹtala, Osu Kẹfa, ọdun 2021.

Amọ lẹyin naa ni iroyin kan gbe e pe Chidinma ni oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun, nitori oun kọ ni oun pa, amọ a ko le fi idi iroyin naa mulẹ.