Bethel Baptist high school Kaduna: Nítòótọ́ lá ń gbé oúnjẹ lọ fún àwọn ajínigbé kí ebi má bàá pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa tí wọ́n jígbé

Bethel Baptist high school Kaduna: Nítòótọ́ lá ń gbé oúnjẹ lọ fún àwọn ajínigbé kí ebi má bàá pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa tí wọ́n jígbé

A máa ń gbàdúrà fún àwọn ajinigbé tí wọ́n bá fẹ́ lọ jí àwọn míì gbé - Akẹ́kọ̀ọ́ Bethel Baptist School Kaduna

Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Aarẹ apapọ ijọ onitẹbọmi ni Naijiria, Nigerian Baptist Convention, oluṣọagutan Israel Akanji ti sọ pe ijọba apapọ ti kuna ninu ojuṣe rẹ lati daabo bo awọn ọmọ Naijiria.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Akanji ni ojuṣe akọkọ fun ijọba ni lati daabo bo awọn araalu.

Akanji lo fi ọrọ naa lede lẹyin ti awọn ajinigbe tu awọn akẹkọọ ijọ onitẹbọmi ti wọn ji gbe ṣaaju ni Kaduna silẹ.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa ṣalaye siwaju si pe awọn ajinigbe naa ko fọwọ kan awọn akẹkọọ naa lọna aitọ, paapaa awọn to jẹ obinrin lara wọn.

Bẹẹ lo tun sọ pe awọn ajinigbe ọhun gba wọn laaye lati maa gbadura gẹgẹ bi ọmọlẹyin Kristi.

O ni wọn gba wọn laye lati maa ṣe isin, bii orin kikọ ati iwaasu lasiko ti wọn wa ni ahamọ.

Aarẹ apapọ ijọ onitẹbọmi naa sọ siwaju si pe awọn ajinigbe naa a maa ke si awọn ọmọ ti wọn ji gbe lati gbadura fun wọn lasiko ti wọn ba fẹ lọ ji awọn eeyan mii gbe.

O pari ọrọ rẹ pe bo ti tilẹ jẹ pe wọn ti ri awọn akẹkọọ naa pada, o ni awọn ṣi n wa awọn akẹkọọ miran to ṣi wa ni ahamọ.

Ẹ wo fidio yo wa loke yii fun ẹkunrẹrẹ.