Saraki arested: Agbẹnusọ EFCC ní àwọn ló fi ìwé pe Saraki

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC ti sọ pe Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, Bukola Saraki ti wa ni ahamọ awọn.

Agbẹnusọ ajọ naa, Wilson Uwujaren sọ fun BBC pe awọn lo fi iwe pe Saraki, ṣugbọn ko ṣalaye eredi ti wọn ṣe fi iwe pe Saraki ni ẹkunrẹrẹ.

Ṣaaju ni awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ti kọkọ jabọ pe Saraki wa ni ahamọ EFCC lori ẹsun to rọ mọ ole jija ati lilu owo ilu ni ponpo.

Saraki ti fi asiko kan jẹ gomina ipinlẹ Kwara ri, iyẹn laarin ọdun 2003 si 2011.

Oun naa tun ni Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria laarin ọdun 2015 si 2019.

Lasiko to wa nile aṣofin agba ni Saraki ti kọkọ n koju oniruru ẹsun to jọ mọ ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ati ẹsun pe ko kede iye dukia to ni.

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Ṣugbọn ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiiria ni ko jẹbi ọkankan lara awọn eṣun ti wọn ka si lẹsẹ lọdun 2018.

Ni bayii ti EFCC tun ti fi iwe pe Saraki, o ṣeeṣe ki wọn tun bẹrẹ iwadii akọtun lori awọn ẹsun to jọ mọ eyii ti wọn ti kọkọ fi kan an ṣaaju.

Iroyin ni EFCC fẹsun kan Saraki pe o kowo ilu sapo labẹ asia awọn ileeṣẹ kan ti wọn ko tii fi orukẹ wọn lede.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...