Ibadan Accident: Tírélà agbépo ṣekúpa ọmọ ìyá méjì àtàwọn mẹ́ta míì

Bi a ṣe n lọ, ti a nbọ, Ọba oke ko ni jẹ ki a ṣi rin o.
Ọmọ iya meji ti wọn n lọ fun idanwo aṣejade ile ẹkọ girama, NECO ni a gbọ pe o wa lara eeyan marun un ti tirela agbepo bẹntiro run mọ inu koto nla lagbegbe Celica niluu Ibadan lọjọ Aje.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ijanu tirela ọhun lo ja, eleyii to jẹ ki o gba taxi ti ero marun un wa ninu rẹ sinu koto ti o si tẹ wọn pa mọ'bẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó fi Chidinma Ojukwu tí wọ́n lo pa Ataga sí ẹ̀wọ̀n
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ìdí rèé táwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà fi wà láhámọ́ títí di ọjọ́ Ajé - Amòfin Yomi Aliyu
- Wo ìgbésẹ̀ tuntun tí DSS ń gbé láti dojú béèlì àwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà bolẹ̀
- Ọwọ́ FBI yóò tẹ Abba Kyari, òǹyẹ̀ kankan kò lè yẹ̀ ẹ́ - Femi Falana
- Akeugbagold sọ̀rọ̀ lórí bóyá ṣíṣe àjọ̀dún Hijra tọ̀nà àbí bẹ́ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ìkéde ọjọ́ ìsinmi
Ni bii ago meje aarọ ọjọ Aje ni ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ lopopona mọrọsẹ Ibadan si Ile Ife.
Ọga ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, Uche Chukwurah fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin mẹta ati obinrin meji lawọn eeyan to ku ninu ọkọ taxi ọhun.
Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́
Ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn ẹṣọ oju popo atawọn panapana ti de sibẹ lati doola ẹmi awọn eeyan.
Bakan naa ni awọn panapana n gbiyanju lati yọ awọn ọkọ mejeeji kuro ninu koto.
Ṣugbọn wọn ko tete ri awọn ọkọ naa yọ lasiko bo ya nitori bi koto naa ṣe jin to lo fa eleyii.
Bi eeyan ba jẹ ori ahun, ti o ba de agbegbe Celica ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ lọjọ Aje yoo bomi loju pẹli bi ọkọ agbepo yii ti pa taxi elero marun un pẹlẹbẹ.
Ẹwẹ, awọn eeyan agbegbe Celica ra ọwọ si ijọba lati pari iṣẹ lori ọna ti o n ṣiṣẹ lori rẹ lagbegbe naa ni kiakia lati le dena iru iṣẹlẹ bayii.
Wọn ni ijamba ọkọ to n ṣẹlẹ lagbegbe naa ti di lemọ lẹmọ nitori ọna ti ko dara nibẹ.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí bọ́ nígbà tí ìjánu tírélà já, ó wó lu ọkọ̀ akérò taxi kan mọ́ inú kòtò n'Ibadan
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn eeyan agbegbe Celica niluu Ibadan ti ke gbajare si ijọba lati pari iṣẹ atunse oju popo to n lọ lọwọ loju ọna marosẹ Ibadan si Ile Ife.
Awọn ara adugbo naa sọrọ yii fun BBC Yoruba lẹyin ti tirela agbepo kan wo lu ọkọ taxi akero kan mọlẹ ninu koto laarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ.
Ohun tawọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju sọ nipe ijanu ọkọ agbepo naa ni ko mu un mọ, to fi ya kuro loju popo, o gba ọkọ taxi akero naa, to si wọ lọ sinu koto nla kan to wa lẹba oju ọna naa pẹlu rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- Mo gbádùn bí wọ́n ṣe ń pè mí ní ''audio governor''- Seyi Makinde
- IPOB àti ìjọba ń lérí lórí òfin kónílé ó gbélé, ta ni yóò tẹríba fúnra wọn?
- Ta ni èṣù láàrin ìjọ Ọlọ́run àti Hushpuppi? - Daddy Freeze bèèrè
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ohun tó ṣe ìdíwọ́ rèé táwọn alátìlẹ́yìn Sunday Igboho méjìlá kò fi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Agbẹjọ́rò
Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Sunday ṣalaye pe ọkọ taxi naa fẹ gbe ero loju popo ni, nigba ti tirela agbepo ti ijanu rẹ ko mu un mọ naa fi gbe ha ẹnu, ti o si lọ run mọ inu koto.
O ṣalaye pe ọkọ meji ni tirela naa gba, ṣugbọn ori ko ọkọ keji yọ.
Sunday ni ero mẹfa lo wa ninu ọkọ taxi ti tirela wo lu mọlẹ ninu koto lagbegbe Celica, to si pa mọto naa mọlẹ pẹlẹbẹ bii ile isana.
Ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn ẹṣọ oju popo atawọn panapana ti de sibẹ lati doola ẹmi awọn eeyan.
Bakan naa ni awọn panapana n gbiyanju lati yọ awọn ọkọ mejeeji kuro ninu koto.
Ẹlomiran ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ pe ọpọ ẹmi lo ti ṣofo lagbegbe naa nitori ọna ti ko dara ti ijọba ti n ṣe lati ọjọ yii lai pari rẹ, igba akọkọ si kọ ree, ti ijamba yoo maa waye alagbegbe naa.
O sọ pe ijamba ọkọ mii ṣẹlẹ lagbegbe yii kan naa ninu eyi ti ero ọkọ bọọsi mejidinlogun ti padanu ẹmi wọn.
Ẹwẹ awọn oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo, FRSC ati awọn panapana to wa nibi isẹlẹ naa kọ lati ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ ọhun.