Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

Awọn agba bọ, wọn ni ko si ohun ti skunrin se, ti obinrin ko le se ju bẹẹ lọ.

Bi ọrọ se ri ree pẹlu obinrin kan, Abimbola Adedigba to n sisẹ titun ẹrọ ọlọyẹ inu mọto, Air Conditioner (AC) se.

Adedigba, ti iya se koriya fun lati kọ isẹ naa, lo ti kọ ọpọ ọmọ isẹ jade ti gbogbo wọn si jẹ ọkunrin.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Adedigba ni o ti to ọdun mẹrindinlogun ti oun ti bẹrẹ isẹ naa, ti ọpọ awọn ọkunrin si maa n wa oun wa lati se atunse AC mọto wọn.

O fikun pe ọpọ ọkunrin lo ni nitori pe oun jẹ obinrin, oun maa jẹ olotitọ, ti oun ko si ja wọn kulẹ ri.

Bakan naa lo fikun pe abilekọ to wa lọọdẹ ọkọ ni ou, ti ọkọ oun si fara mọ isẹ ti oun n se, eyi to maa n jẹ ki oun wa laarin awọn ọkunrin lọpọ igba, toun si tun ni awọn ọkunrin bii onibara.

O wa kede pe afojusun oun ni lati se rere nidi isẹ naa, ki oun si ni abule mẹkaniki toun ni ọjọ iwaju.