Kwara Kidnap: Ọlọ́pàá ní agbègbè Oke Onigbin àti Omu Aran ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Oríṣun àwòrán, Nigeria News
Awọn eeyan mẹtala miran tun ti ko si ọwọ awọn ajinigbe nipinlẹ Kwara.
Ninu wọn ni eeyan mẹfa kan to n dari lati ibi inawo igbeyawo ni ipinlẹ Ekiti wa.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara Ajayi Okasanmi lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.
O sọ pe laarin aala Kwara ati Ekiti ni awọn ajinigbe naa ti da awọn eeyan meje to n dari bọ lati ibi inawo igbeyawo ni Ekiti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- IPOB àti ìjọba ń lérí lórí òfin kónílé ó gbélé, ta ni yóò tẹríba fúnra wọn?
- Ta ni èṣù láàrin ìjọ Ọlọ́run àti Hushpuppi? - Daddy Freeze bèèrè
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ohun tó ṣe ìdíwọ́ rèé táwọn alátìlẹ́yìn Sunday Igboho méjìlá kò fi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Agbẹjọ́rò
- Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abba Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù
- Buhari ná ₦5trn lórí ètò àbó síbẹ̀ Boko Haram, agbébọn pa 11,420 ọmọ Nàìjíríà - Ìwádìí
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
''Ibi ti wọn ti ko si ọwọ ajinigbe wa laarin Oke Onigbin ati Omu Aran ni nkan bi ago marun un abọ irọlẹ ọjọ Abamẹta.''
Isẹlẹ ijinigbe keji waye laarin Ekan Meje ni ijọba ibilẹ Oke-Ero ni ipinlẹ Kwara ati Ekiti.
Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́
Ninu awọn to ko si gbaga awọn alaburu yi ni Pasitọ kan iyawo rẹ ati awọn eeyan mẹrin.
Okasanmi to fidi isẹlẹ yii mulẹ ni awọn ti doola eeyan mẹjọ lapapọ.
Mẹrin ninu isẹlẹ ti Omu Aran, mẹrin mii ninu ti Oke Onigbin.
Amọ sa o ni awọn ko ti ribi doola Pasitọ ati iyawo rẹ to fi mọ eeyan mẹta to ku ninu awọn to n dari bọ lati ibi ayẹyẹ igbeyawo ni Ekiti.
''Agbarijọpọ awọn ikọ ẹsọ alaabo ati awọn fijilante lo le awọn ajinigbe naa wọnu igbo, taa si ri eeyan mẹrin doola.
A si n gbiyanju lati doola awọn mẹta to ku ninu awọn to lọ si ibi igbeyawo''
Okasanmi pari ọrọ rẹ pe, iwadii n tẹsiwaju ati pe awọn ti ri awọn afurasi kan mu lori isẹlẹ ọhun.
Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún