Sunday Igboho and 12 Suspects: DSS ń gbé ìgbésẹ̀ tuntun láti dojú béèlì àwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà bolẹ̀

aworan Igboho atawọn eeyan mejila naa

Ileeṣẹ agbofinro DSS ti kọwe si onidajọ Obiora Egwuatu ti ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja pe ko wọgile beeli to fun awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho ti ile ẹjs naa gba beeli wọn laipẹ yii.

Ninu iwe ipẹjọ tuntun naa ti wọn kọ, eyi ti akori rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/647/2021 eyi ti agbẹjọro fun Sunday Igboho, Idowu Awo pe, DSS n fẹ ki Onidajọ Egwuatu wọgile aṣẹ beeli to pa lori Amudat Babatunde, Abideen Shittu, Jamiu Oyetunji ati Bamidele Sunday.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ agbofinro DSS n fẹ ki ile ẹjọ wọgile beeli naa ki o si fun awọn laṣẹ ati fi wọn sinu ahams pada titi ti wọn o fi gbe wọn wa sile ẹjọ pada lasiko isinmi ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf

Amọṣa, agbẹjọro fun awọn eeyan mejila ti wọn ko nile oloye Sunday Igboho naa, Amofin Pẹlumi Jẹngbesi ti ṣalaye fun iwe iroyin The PUNCH pe awada kẹrikẹri ni igbesẹ ti ileeṣẹ agbofinro DSS ngbe yii.

Ni Ọjọru ọsẹ to kọja ni Onidajọ Obiora Egwuatu gba beeli awọn mejila naa lẹyin ti wọn lo ọsẹ marun un ni ahamọ awọn agbofinro DSS naa lẹyin ti wọn mu wọn lasiko ti awọn oṣiṣẹ DSS kan kọlu ile Igboho nilu Ibadan ni nnkan bii agogo kan oru ni Ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021.