Sunday Igboho and 12 Suspects: Yomi Aliyu ní àwọn ti parí ìlànà tó yẹ́ ọ̀rọ̀ kù sọ́wọ́ àdájọ́ àti ilé ẹjọ́

Awọn ọmọlẹyin Sunday Igbohun tawọn DSS mu ni ile rẹ.

Oríṣun àwòrán, others

Ni Ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni ileẹjọ giga kan nilu Abuja gba beeli awọn eeyan mejila ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS ko nile oloye Sunday Igboho nilu Ibadan.

Onidajọ Obiora Egwuatu paṣẹ pe ki wọn gba beeli awọn eeyan naa, bi o tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ DSS gbiyanju titi lati yi igbesẹ naa pada.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa lẹyin ọjọ marun un ti aṣẹ yii ti waye, awọn eeyan mejila yii ko tii kuro ni ahamọ awọn agbofinro DSS.

Eyi kii ṣe nitori pe awọn oṣiṣẹ naa ko fẹ fi wọn silẹ o, bikoṣe pe awọn agbofinro wọn ko tii mu awọn gbedeke ti ile ẹjọ la kalẹ fun gbigba beeli wọn ṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lọsan ọjọ Aje, ọjọ Kẹsan osu Kẹjọ ọdun 2021, agba amofin Yọmi Aliyu SAN ṣalaye pe, awọn eeyan mejila naa ti wa nile ẹjọ nibi ti awọn amofin ti n ṣe eto gbogbo lati rii pe awọn ilana antẹẹle ti ile ẹjọ gbe kalẹ fun beeli wọn, wa si imuṣẹ.

Bakan naa nigba ti BBC News Yoruba beere pe ṣe awọn eeyan mejila yii yoo wale lọjọ Aje, o ni eyi ku si ọwọ adajọ ati ile ẹjọ.

O fi kun un pe, wọn ti ṣeto gbogbo to yẹ lọdọ awọn agbofinro DSS, wọn si ti wa nile ẹjọ lati lee yanju ohun gbogbo to ba yẹ.