Custom Service: Báwo ní ẹ̀mí mẹ́fà ṣe bọ́ lásìkò táwọn aṣọ́bodè ń lé onífàyàwọ̀ láàrín ìlu?

Awọn asọbode da ọkọ kan duro loju popo

Oríṣun àwòrán, NNN

Eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn nigba ti ọkọ awọn osisẹ asọbode Naijiria kọlu awọn eeyan to wa lẹgbẹ titi nilu Jibia, ipinlẹ Katsina.

Lowurọ ọjọ Aje ni isẹlẹ yii waye, ninu eyi ti eeyan oogun mii ti farapa.

Jibia jẹ ilu kan to wa lẹgbẹ ibode Naijiria pẹlu orilẹede Niger, ti pupọ awọn eeyan ibẹ si maa n se karakata laarin ilẹ mejeeji.

Ijamba ọkọ naa lawọn ti isẹlẹ ọhun soju wọn sọ pe o waye nigba tawọn osisẹ asọbode n le awọn afurasi onifayawọ kan, to wa ninu ọkọ J5 Peugeot.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Dẹrẹba ko ribi dari ọkọ mọ, lo mu ko rọlu awọn eeyan to wa lẹgbẹ titi'' ni alaye ti olugbe agbegbe naa, AlMustapha Danye se.

O ni ''lẹsẹkẹsẹ ni eeyan mẹfa ku, ti wọn si gbe awọn to farapa lọ si ileewosan ni Jibia. Mo gbọ pe awọn mii ku ninu wọn sugbọn mi o le fidi ọrọ yi mulẹ nitori mi o ba wọn de ibẹ''

Àkọlé fídíò,

Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin

Bi ijamba naa se waye ree:

Onisowo kan Kabir Jibia ti isẹlẹ naa soju rẹ ni nkan bi ago mẹjọ aarọ lo waye.

"Ọlọkọ to ni J5 Peugeot yẹn wa lara awọn to maa n ra agbado lati ilu Dandume lati wa taa ni ibi. Wọn maa n saba fun awọn asọbode ni owo toun ti pe kii se isẹ fayawọ ni wọn se.''

O ni sugbọn onimọto yii kọ lati duro nibi ti wọn ti da duro ni Batsari, bi eeyan ba ti n pada bọ wa si Jibia.

"Wọn fi ọkọ le lati ibẹ wọ inu ilu. Nigba ti wọn sare tẹle ni ọkọ wọn ya lọ ba awọn eeyan to wa lẹgbẹ titi."

Arakunrin Jibia fikun pe awakọ J5 naa mọ oju ọna ilu daada ati pe o ti sa mọ awọn asọbode naa lọwọ.

Ọgbẹni Danye ni tiẹ sọ pe awọn asọbode naa fẹsẹ fẹẹ ni kete ti ijamba ọkọ yi waye.

''Nibẹrẹ nise lawọn eeyan n gbiyanju lati doola awọn ti o ha si ẹnu ọkọ sugbọn nigba ti wọn ri ti awọn asọbode sa lọ, ni wọn ba fi ibinu dana sun ọkọ wọn''

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

Ki ni awọn ileesẹ asọbode sọ?

Alukoro ileesẹ asọbode to wa ni Katsina, Danba Isa sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ tawọn eeyan sọ pe awọn n fi ọkọ le eeyan ni.

O ni "ohun taa mọ ni pe ijamba ọkọ lo waye, ko si si ẹni ti iru rẹ ko le sẹlẹ si. Ijamba naa waye lowurọ oni lẹyin tawọn osisẹ wa jẹun tan, ti wọn si n pada si ẹnu isẹ wọn.

Nigba ti wọn n lọ ni ijanu ọkọ kọsẹ, to si fa ijamba ọkọ naa''

Arakunrin Isa wa kesi awọn araalu lati sinmi gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri.

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó fi Chidinma Ojukwu tí wọ́n lo pa Ataga sí ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, other

Ile ẹjọ Majisireti kan ni Yaba, nipinlẹ Eko ti ju Chidinma Ojukwu, ti wọn fi ẹsun kan pe o pa oludasilẹ ileesẹ amohunmaworan Super TV, Usifo Ataga, si ẹ̀wọ̀n fun ọgbọn ọjọ.

Ọjọ Aje ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko gbe Chidinma to jẹ akẹkọọ Fasiti UNILAG, ati afurasi meji miran, lọ si ile ẹjọ naa.

Onidajọ Adeola Adedayo pàṣẹ pe ki wọn o fi si ẹ̀wọ̀n naa, titi ti ileesẹ eto idajọ yoo fi sọ nkan to ku lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni wọn gun Ọgbẹni Ataga pa sinu ile kan nipinlẹ Eko, ki ọwọ to o tẹ Chidinma to jẹ ọrẹbinrin rẹ.

Saaju ni ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun jẹwọ pe ẹẹmeji ni oun gun Ataga ni ọrùn lasiko to fẹ ẹ fi ipa ba oun ni ibalopọ.

Sugbọn o tun pada sọ pe oun ko mọ nipa iku rẹ. O ni oun lọ ọ ra oúnjẹ lasiko naa, ati pe bi oun ko ṣe fi ọrọ iku rẹ to ileesẹ ọlọpaa leti, ati bi oun tun ṣe gba owo ninu apo àsùnwọ̀n rẹ ni banki, ni ẹbi ti oun jẹ