Adebimpe Oyebade: Láti yunifásítì títí dé àgbo tíátà láwọn ọkùnrin tí n fẹ́ bámi ní ìbálòpọ̀

Adebimpe Oyebade

Oríṣun àwòrán, Instagram/mobimpe

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba Adebimpe Oyebade ti tu kẹkẹ ọrọ lori ohun ti oju rẹ n ri lagbo oṣere tiata.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣe iroyin Naijriia This Day, adumaradan oṣere awẹlẹwa yi sọ pe nigba ti oun ti darapọ mọ Nollywood lawọn ọkunrin ti n gbiyanju lati ni ibalopọ pẹlu rẹ.

Adebimpe ṣalaye pe iru nkan bayi gbode kan ati pe ni ti toun lati igba toun ti wa ni ile ẹkọ fasiti ni oun ti n koju ipenija yi.

''Mi o le sọ pe mi o koju rẹ. Idi ta si fi n sa nipa iru iwa yi lagbo oṣere ni pe ojutaye la wa.''

''Nigba ti mo jẹ akẹkọọ fasiti, alamojuto mi ninu idanwo aṣekagba(project supervisor )fi ibalopọ lọ mi''

O ni nitori iriri oun, iru nkan bayi lagbo tiata ko jẹ iyalẹnu rara.

''Awọn obinrin ni mo da lẹbi bi awọn ọkunrin ṣe n fi ibalopọ lọ wọn. Idi si ni pe awa gan-an la maa n faaye gba wọn lati fi ibalopọ lọ wa.''

O tẹsiwaju pe bo ba ṣe pe awọn obinrin kii gba iru nkan bẹẹ ni, awọn to ti wa sọ di iṣẹ ko ni maa ṣe bẹ fun wọn.

''Oju mi ri to pẹlu awọn onilọkulọ nigba ti mo de Nollywood. O ṣu mi debi pe mo n beere pe ṣe mi o ti ṣi ọna ya si bayi. Ati oṣere ati oludari gbogbo wọn ni wọn n gbiyanju lati bami lajọṣepọ''

Nigba ti wọn wa beere lọwọ rẹ pe bawo lo ṣe bori awọn wọn yi, Adebimpe ni oun jẹ ki o yé awọn ọkunrin naa pe ko di dandan ki oun kopa ninu ere wọn.

Àkọlé fídíò,

Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

O ni ọpọ eeyan lo maa n ṣe ohun ti ko bojumu nitori ki wọn baa le jẹ ilumọọka ṣugbọn ko ri bẹẹ lọdọ toun.

''Ki eeyan to le de ibi giga, o gba a suuru ati ki eeyan tẹra mọ iṣẹ. Mo mọ eeyan pupọ ṣugbọn kii ṣe gbogbo eeyan naa lo ri bẹ''