2022 Budget: Ìjọba Nàìjíríà fẹ́ yá N4.89 tirilọ̀nù láti san gbèsè ètò ìṣúná

Eniyan to nka owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin obitibiti gbese ti orilẹ-ede Naijiria ti jẹ, ijọba apapọ tun ti n gbero lati ya owo to to N4.89 tiriliọnu owo naira fún eto iṣuna ọdun 2022.Minisita eto inawo, Zainab Ahmed lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ yii l'Abuja.Minisita Ahmed ni owo ti ko wọle daadaa to fun Naijiria lo maa jẹ ki ijọba ya owo yii lati le loo fun eto iṣuna N13.98 tiriliọnu ti ijọba n gbero fun ọdun to n bọ.

Minisita ṣalaye ọrọ yii bakan naa fun igbimọ ile aṣoju-ṣofin to n ri si eto inawo.Hajia Ahmed ni bi owo Naira ṣe ja lulẹ sí dọla ati pọun naa ṣe akoba fun owo to n wọle fún orilẹ-ede Naijiria.Minisita ni ijọba gbé ìgbésẹ lati ya owo san gbese N5.62 tiriliọnu ninu eto iṣuna ọdun 2022.Bakan naa ni minisita tun ṣalaye pe ijọba ti din iṣẹ akanṣe ku fun ọdun 2022 .

Àkọlé fídíò,

Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Minisita ṣalaye pe owo to to N259.315bn ni ijọba fi ṣe adinku iṣẹ akanṣe fun ọdun 2022.Hajia Ahmed ni eyi waye nitori bi ọrọ aje Naijiria ti n ṣe ojojo ati bi ajakalẹ arun covid-19 ti ṣakoba fun ọrọ ajé."Ni bayii, N1.76trn ni ijọba yoo na lori iṣẹ akanṣe lọdun 2021 eyi to kere si N2.02trn ti ijọba na lọdun 2021.

N410.15 ni a fi ṣe gbedeke pasipaarọ owo naira sí dọla nigba ti a fi $57 dọla ṣe gbedeke owo agbaa epo rọbi fun eto iṣuna," minisita ṣalaye.Mínísítà fikun ọrọ rẹ pe awon ẹka ọrọ ajé mii yatọ sí epo rọbi dagba pẹlu owo to to N169.69trn.