Sunday Igboho Aides: Lẹyìn tí gbogbo ètò tó àwọn amúgbálẹ̀gbẹ́ kò rí adájọ́ tí yóò buwọ́lù béèlì wọn

Aworan awọn amugbalẹgbẹ Igboho ninu ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Punch

Bi iya n la ba gbeni sanlẹ,Yoruba ni kekere a maa gun ori ẹni.

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu bawọn amugbalẹgbẹ Sunday Igboho ti adajọ ni ki wọn lọ ṣeto beeli wọn ko ṣe ri adajọ lẹyin ti gbogbo eto beeli wọn pe tan.

Idi ni pe adajọ to yẹ ko buwọlu iwe itusilẹ wọn ti ṣe irinajo pajawiri lọ si ilẹ okere.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Naijriia Punch ṣe jabọ, agbẹjọro awọn ti o wa ni ahamọ DSS wọn yi,Pelumi Olajengbesi, sọ pe gbogbo nkan ti adajọ Obiora Egwuatu ni ka wọn ṣeto lawọn ti ṣe.

O ni ṣugbọn o jẹ iyalẹnu pe adajọ ile ẹjọ giga yi nilu Abuja ko si lorileede Naijiria.

Olajengbesi ni oun lọ si ọfisi ti wọn ti n ṣeto beeli awọn eeyan lọjọ Iṣẹgun ṣugbọn o ni wọn sọ fun oun pe adajọ ti rinrinajo kuro ni Naijiria

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf

''Gbogbo eto beeli la ti se ti igbakeji akọwe ile ẹj si ti buwlu.Sugbọn awọn to wa ni ọfisi beeli ni adajọ to yẹ ko buwọlu iwe yi ti lọ fun idanilẹkọ kan ko si ni pada de titi di ọsẹ to n bọ''

Agbẹjọro yi sọ pe ọgbọn ki wọn baa le fi awọn amugbalẹgbẹ Igboho si ahamọ fọsẹ kan si lẹyin ti wọn ti ti wọn mọlẹ fun aadọta ọjọ ni wọn n da.

Ni ọjọ Kẹrin oṣu Kẹjọ ọdun 2021 ni adajọ Egwuatu ti gba pe ki wọn tu awọn amugbalẹgbẹ yi silẹ lẹyin ti wọn ba ṣeto beeli wọn tan.