Sunday Igboho aides: Ó ṣeéṣe kí adájọ́ míràn buwọ́lu ìwé béèlì àwọn méjìlá tí DSS mú nílé Igboho lónìí

Awọn ọmọlẹyin Sunday Igbohun tawọn DSS mu ni ile rẹ.

Oríṣun àwòrán, others

Adajọ tuntun ni ile ẹjọ giga apapọ to wa nilu Abuja ni ireti wa pe yoo buwọlu iwe aṣẹ beeli awọn eeyan mejila ti awọn agbofinro DSS ba ni ile aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn iroyin abẹle gbogbo n sọ, awọn eeyan mejila naa ti mu gbogbo gbendeke ti adajọ Egwuatu to gbọ ẹjọ wọn la kalẹ fun beeli wọn ṣẹ.

Iroyin sọ pe, ọkan lara awọn agbẹjọro fun awọn eeyan mejila naa, Amofin Pẹlumi Ọlajẹmgbesi kan si ẹka to n mojuto ọrs beeli ni ile ẹjs naa ni ọjọ Iṣẹgun lati yan adajọ miran ti yoo buwọlu iwe beeli awọn eeyan naa.

O ti to nnkan bii aadọta ọjs ti awọn eeyan mejila naa ninu eyi ti obinrin kan wa ti lo ni ahamọ awọn DSS bayii.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn mu awọn eeyan mejila naa si ahamọ, agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho, Amofin agba Yọmi Aliyu, San ṣalaye pe awọn agbofinro DSS ko fun awọn eeyan naa lanfani ati tọju ara wọn koda eyi to n jẹ obinrin ninu wọn gan ko lanfani si awọtẹlẹ tuntun yatọ si eyi to baa kuro nile lọjọ ti awọn oṣiṣẹ DSS kọlu ile Igboho ni ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021.

Àkọlé fídíò,

Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'

Ọlajẹmgbesi sọ ṣaaju pe ẹka to n mojuto ọrọ beeli nile ẹjọ naa ti kọkọ ṣalaye fun oun lọjọ Iṣẹgun pe Onidajọ Obiora Egwuatu to yẹ ko buwọlu iwe aṣẹ beeli wọn ti rinrinajo lọ si oke okun lati moju to ohun kan ni kiakia.

O ṣalaye fun iwe iroyin The Punch pe Onidajọ Egwuatu lo yẹ ko buwọlu iwe naa ki o to di pe o lọ soke okun.

Àkọlé fídíò,

Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Lara gbendeke ti Ile ẹjọ beere fun beeli awọn eeyan naa ni oniduro mejimeji, ti apapọ rẹ fi jẹ mẹrinlelogun eleyi to mu idiwọ diẹ ba ijafafa ati gba beeli wọn lẹyin ti adajọ ni aye beeli yọ fun wọn nibi igbẹjọ to waye lọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2021.