Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board' pẹ̀lú ọ̀nà àti ta ọjà ló mú kí fíìmù oníhòhò ó pọ̀ lórí igbá

Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board' pẹ̀lú ọ̀nà àti ta ọjà ló mú kí fíìmù oníhòhò ó pọ̀ lórí igbá

Iṣẹ ere itage, sinima agbelewo ṣisẹ kii ṣe iṣẹ alagbe mọ gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n fi oju woo ni igba kan sẹyin. O ti di iṣẹ to n jawo, to n mu ọpọlọpọ biliọnu dọla owo ilẹ Amẹrika wọle pẹlu.

Amọṣa ohun kan ti o n kọ ọpọ lominu ni pe pẹlu bi iṣẹ yii ti ṣe gbẹrẹgẹjigẹ to bayii, awọn ohun kan to n waye nibẹ n ṣe akoba fun awujọ, ninu eyi ti bi ṣiṣi ara silẹ awọn oṣere, papajuls awọn to jẹ obinrin ninu wọn ṣe wa di tọrọ fọnkale.

Gbajumọ Oṣere Rose Odika to ba BBC News Yoruba sọrọ ninu ifọrọwerọ yii ṣalaye pe lootọ ohun to ku diẹ kaato ni eyi ṣugbọn ọna ti jẹ naa ni nitori gbogbo awọn to n gbe sinima jade lo n gbero ati ta ata jere ọja. O fi kun un pe lọpọlọpọ igba ti awọn oṣere ba gbe fiimu to fọnrere aṣa wa jade, gbogbo awọn to n kọminu lori ṣiṣi ara silẹ wọn naa ni kii raa, bẹlni owo yoo wọgbo ti yoo si di gbese si ọrun oṣere bẹẹ.

Bakan naa lo ṣalaye pe ijọba gbe ajọ ayẹwo kan kalẹ gẹgẹ bi ọlọpaa to n ṣọ iṣẹ ti awọn oṣere n gbe jade, ti a pe ni Nigeria Censors Board. O ni ko si sinima kan to n jade lorilẹede Naijiria ti ajọ yii ko mọ si, nitorina naa to ba jẹ pe lootọ ni wọn n ṣe iṣẹ wọn ni, ko yẹ ki iru awọn ohun ti a n sọrọ rẹ yii tun maa jẹyọ.