Goriola Hassan: Bí o ko ba yọju níwájú ilé, a ó fi ọlọ́pàá gbé ọ́, Alaga Igbimọ pàsẹ fún Goriola Hassan lórí ipò rẹ̀ bi ọba Imobi

Goriola Hassan

Oríṣun àwòrán, other

Ile igbimọ asofin ipinlẹ Ogun tun ti ke si ọgbẹni Goriola Hassan lati farahan niwaju igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ ijọba ibilẹ ati ifinijoye lori wahala to wa nilẹ nipa ipo ọba ilu Imobi-Ijebu.

Ipo Goriola gẹgẹ bi ọba Imobi ti n da gbọmisi-omi-o- to silẹ

"O yẹ ki o faraha niwaju ile igbimọ asofin ipinlẹ Ogun ni ọjọ keji osu kesan-an ni aago mọkanla owurọ.

Igbimọ tẹẹkoto ti Bolanle Ajayi n se alaga rẹ tun kọwe ipe ranṣẹ si Hassan lasiko ipade wọn fun igba keji lori ẹsun ti awọn ẹgbẹ ọmọ ibilẹ Imobi kan mu lọ sile asofin nitori ipo ọba to wa ni ilu Imobi.

Ijoko keji yii ni awon lọbalọba to wa fun ipade naa to fi mọ Onitasin ti Itasin, Oba Adenola Adegbesan, ati awọn Baalẹ ti ọrọ kan lati agbegbe

Ajayi ati awọn ọmọ ile to ku ti paa lasẹ lati sinmi pipẹ ararẹ ni Olu ri Imobi nitori ijoba ipinlẹ Ogun ti kọwe ransẹ si lati ipase ile isẹ ijọba to n ri si ọrọ ijoba ibilẹ ati ifinijoye.

Àkọlé fídíò,

Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Alaga Igbimọ naa fi kun pe ti Hassan ba kọ lati gbọnran si ipe ile igbimọ asofin, bi o se kò lati wa fun meji akọkọ, eyi yoo mu ki awọn pe ọlọpaa lati mu.

Saaju ni abẹnugan ile Olakunle Oluomo sọ pe Goriola kan si oun ni ọsẹ lori ọrọ naa ri oun si sọ fun pe kosi sise ko si aiṣe ki o kọkọ yoju si ipe awon igbimọ tẹẹkoto, nitori ile ti ro wọn lagbara lati se iwadii ọrọ naa, lẹyin ti awọn ara ilu ti kọ iwe ẹsun si ile igbimọ asofin