Gómìnà Aminu Masariì ti ipínlẹ̀ Katsina ní àsìkò tó kí aráàlú ó lọ ra ìbọn láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn agbébọn

Gomina Masari ati awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, other

Ọrọ abo lorilẹede Naijiria ti di eyi to so ọlọgbọn ati omugọ kọ bayii; oniruru ọna abayọ si lo n jade lati koju rẹ.

Nibayii, gomina ipinlẹ Katsina lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria, Aminu Masari ti ke sawọn araalu lati lọ wa ibọn atawọn ohun ija miran lọnakọna lati gbeja ara wọn lọwọ awọn janduku agbebọn to n jinigbe pawo bayii.

Ipinlẹ Katsina wa lara awọn ipinlẹ ti iwa ipa yii pọ ju si bayii bẹẹni apa awọn oṣiṣẹ agbofinro ko fẹrẹ kaa mọ.

Gomina Aminu Masari di ẹbi ru awọn araalu fun bi awọn agbebọn ṣe n ṣọṣẹ kaakiri.

O ni bi awọn araalu ṣe maa n jọwọ ara wọn silẹ bi ọlẹ ati ojo n tubọ mu ki awọn agbebọn naa o laya sii lati ṣe iṣẹ buruku wọn.

Lasiko abẹwo rẹ si ilu Jibia, ọkan lara awọn ileto to n fara kaasa ikọlu awọn janduku agbebọn wọnyii ni gomina Aminu Masaari sọ ọrọ yii.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, minisita fọrọ abo lorilẹede Naijiria lo kọkọ gbe aba yii kalẹ loṣu keji ọdun 2021 eleyi to mu ki ọpọlọpọ eeyan o bu ẹnu atẹ luu nigba naa.

Àkọlé fídíò,

Kola Ologbondiyan: PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023

Ọpọlọpọ lo n foju wo ọrọ wọnyii gẹgẹ bi ọna kan ti ijọba fi n ta araalu lolobo nipa ijakulẹ wọn lori ọrọ abo ati ṣiṣi ojuṣe idaabo bo ara ilu pada sori araalu funra wọn.

Bakan naa lawọn lamẹtọ kan naa tun n jẹ ko di mimọ pe atunbọtan irufẹ ipe bayii to ba bọ sii yoo buru pupọ fun ọrọ abo ilu gan an.