Amotekun: Ikọ̀ Amotekun ní àwọn kọ́ ló pa ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Ibadan, ọ̀tọ̀ ní ibi tí àwọn ti ṣiṣẹ́ lóru Ọjọ́bọ

Adari ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo, Ajagunhfeyinti Olayinka Olayanju ti ṣe alaye wi pe ikọ ẹsọ alaabo naa ko mọ ohunkohun nipa iku ọmọ ọdun meedogun ti ọta ibọn da ẹmi rẹ legbodo loru mọju Ojoru ni agbegbe Mokola nilu Ibadan.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ lowurọ Ojoru ni olu ileese ikọ naa to n bẹ ni agbegbe Dandaru nilu Ibadan, Olayanju ṣalaye fun awon akọroyin pe ọtọ ni ibi ti ikọ naa ti ṣiṣẹ loru mọju ọjọ naa.
O tẹsiwaju pe ikọ Amotekun gba ipe pajawiri ni oru Ojoru ni agbegbe Sango nilu Ibadan, ibẹ si ni wọn yara lọ lati doola ẹmi awọn eeyan ti awọn ole ati ọdaran n da laamu.
O fi kun ọrọ rẹ pe nnkan iyanu gbaa ni bi iroyin ṣe gbode kan lowurọ Ojoru wi pe ikọ Amotekun ṣekupa ọdọkunrin kan ni agbegbe Mokola.
- Gómìnà ìpínlẹ̀ kan rèé tó ní kí aráàlú ó lọ ra ìbọn láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn agbébọn
- Èyí lohun tí Amòfin àgbà Nàìjíríà, Malami sọ níléẹjọ́ lónìí nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lu Fulani àti ìkọlù tó wáyé nílé Igboho
- Àlàyé rèé lórí nkan tó pa èèyàn méje nínú ẹbí kan ní ìpínlẹ̀ Osun
- Oní Típà tó bá ta yanrìn ní iye owó tí a kò fọwọ́ sí yóò fojú balé ẹjọ́ - Ijọba ìpínlẹ̀ Ondo
Ọkan lara awọn aṣoju agbegbe Sango ti ikọ Amotekun se abewo si loru moju, Arakunrin Olusola Olaleye naa ṣalaye fun akọroyin BBC pe looto ni awọn ke pe ikọ Amotekun ni nnkan bii aago kan aabọ oru nitori awọn igara ọlọṣa to n yọ awọn lẹnu lagbegbe naa lati bi oṣu melo kan sẹyin.
O ni gbogbo irin ti Amotekun rin loru mọju ko gba ọna Mokola ti wọn ti pa ọmọkunrin ẹni ọdun meedogun.
L'owuro Ojoru ni ọgọrọ awọn ọdọ lati agbegbe Mokola gbe oku ọmọkunrin naa lọ si olu ileese Amotekun ati ofisi gomina ipinle Oyo pẹlu ẹsun pe ikọ Amotekun lo ṣekupa ọmọ naa ṣugbọn ikọ naa jiyan ọrọ.
Ìdàrúdàpọ̀ ní Mokola nílùú Ibadan nítorí òṣìṣẹ́ Amotekun tó yìnbọn fún ọmọ ọdún 15 kan
Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'
Iroyin yajoyajo lati ilu Ibadan n fidi rẹ mulẹ pe igboro ti daru lagbegbe Mọkọla nilu Ibadan lẹyin ti oṣiṣẹ Amọtẹkun kan yinbọn fun ọmọ ọdun marundinlogun kan nibẹ.
Awọn ọdọ kan bẹrẹ si nii wọde lọ si Sẹkitariati ijọba ipinlẹ Ọyọ lori bi awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ ṣe yinbọn fun awọn ọdọ kan.
- Ìjọba gbẹ́sẹ̀lé iṣẹ́ ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ Típà àti oníkùsà ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Àlàyé rèé lórí nkan tó pa èèyàn méje nínú ẹbí kan ní ìpínlẹ̀ Osun
- Ó ṣeéṣe kí adájọ́ míràn buwọ́lu ìwé béèlì àwọn méjìlá tí DSS mú nílé Igboho lónìí
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí ọlọ́pàá Cotonou ṣe kọ́kọ́ fi ẹ̀wọ̀n so Sunday Igboho ní àhámọ́
Awọn oluwọde naa n ṣalaye pe ọdọmọdekunrin ọms ọdun marundinlogun ti wọn yinbọn naa ti jade laye ati pe o yẹ ko ba wọn joko ṣe idanwo aṣekagba girama WAEC lọwọlọwọ bayii.
Awọn ti iṣẹlẹ naa tun ṣoju wọn ṣalaye pe Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye.
Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ siwaju, akẹkọọ na n fẹ lọ ounjẹ ti yoo jẹ lagbegbe Sabo nilu Ibadan ni wọn fi ṣiimu gẹgẹ bi adigunjale ti wọn si yin in nibọn.
Awọn oluwọde naa ti gbe oku ọmọ naa kuro ni Mọkọla lọ si Sẹkitariati agodi .