Ghana Reverend Father Kiss: Àlùfáà Obeng Larbi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fi ẹnu kò lẹ́nu

Aworan bi Fada se n fi ẹnu ko awọn akẹkọọbinrin

Oríṣun àwòrán, Other

Alufaa ijọ Anglican , Baltharzzar Obeng Larbi to fi ẹnu ko awọn akẹkọọbinrin lẹnu laipẹ yii ti tọrọ aforiji lọwọ awọn akẹkọọ naa.

Bakan naa lo tun tọrọ aforiji lọwọ awọn ẹbi wọn, ati ijọ Ọlọrun to fi mọ gbogbo araalu.

Ọsẹ to kọja ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan Alufaa Larbi, bo ṣe n fi ẹku ko awọn akẹkọọbinrin mẹta lẹnuwo, lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ kan nile ẹkọ wọn, St. Monica College of Education, lorilẹ-ede Ghana.

Alufaa Larbi sọ pe oun n gbiyanju lati ki wọn fun bi wọn ṣe tayọ lẹnu ẹkọ wọn, paapaa bi wọn ṣe n lọ fun iṣẹ ode.

O ni akẹkọọ ipele kẹta ni awọn ọmọbinrin naa, ti wọn si n lọ fun iṣẹ ode ti wọn n pe ni 'teaching practice' ni ede Gẹẹsi.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Alufaa naa sọ pe ki gbogbo eniyan dari jin oun, ki wọn o si gbadura fun un lasiko idanwo yii.

"Mo tọrọ aforijin fun awọn nkan ti mo ṣe ninu fidio naa. O daju pe mo ti fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn nkankan . Mo gba pe iwa mi ko bojumu nibi to ti ṣẹlẹ, bi ko tiẹ si Covid-19 nita."

Àkọlé fídíò,

Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Lẹyin ti fidio naa jade sita ni awọn alaṣẹ ijọ Anglican gbe igbimọ kalẹ lati wadii ọrọ naa, ti wọn si jẹjẹ pe awọn yoo ba Alufaa Larbi wi pẹlu ofin ati ilana ijọ wọn.

Lẹyin wakati mẹrinlelogun ni wọn paṣẹ fun alufaa naa lati fi isẹ silẹ fun igba diẹ, gẹgẹ bi alufaa ile ẹkọ naa, titi iwadii yoo fi pari.

Ti wọn si tun sọ pe eto igbani ni imọran ti n waye fun awọn akẹkọọbinrin naa, lati le dena ibanujẹ ọkan to le fẹẹ jade nipa iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Ọlatunji, akẹ́kọ̀ọ́gboyè 'graduate' tó ń ta àkàrà 'Ó ta lẹ́nu' nílùú Osogbo

Aráàlú yarí pé Fadá tó 'kiss' akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lè fipá bá ọmọdé lòpọ̀

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ to waye nile ẹkọ olukọni agba ti St Monica nilu Kumasi, lorilẹede Ghana.

Ayẹyẹ ikẹkọọjade lo n waye nile ẹkọ naa to jẹ ti ijọ Anglican, ti Fada Balthazar Obeng Larbi si jẹ Alufa ile ẹkọ naa.

Amọ Fidio kan to gba ori ayelujara kan lẹyin ayẹyẹ ikẹkọjade naa, lo se afihan Fada yii, to n fi ẹnu ko awọn akẹkọbinrin mẹta lẹnu lara awọn akẹkọọjade naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, ọpọ awọn alejo lo wa ninu gbọngan ti ayẹyẹ naa ti n waye lo n patẹwọ fun lasiko ti Fada naa gbe ẹnu si ẹnu awọn akẹkọọ ọhun.

Isẹlẹ yii si lo waye lasiko ti abala kẹta ọwọja arun arun Coronavirus n peleke si lorilẹede Ghana.

Fidio naa, ti ko to isẹju kan, lo n se afihan Fada Obeng Larbi yii, nibi to ti n fi ẹnu ko ikọọkan awọn akẹkọbinrin naa lẹnu.

Àkọlé fídíò,

Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'

Akẹkọbinrin kẹta to lo ibomu lo kọkọ tiiri ara lati fi ẹnu ko Fada lẹnu amọ ti alufa naa ni ko yọ ibomu rẹ lati gba "kiss" oun.

Fidio yii lo ba ibinu ọpọ eeyan pade lori ayelujara, ti wọn si n pe Fada naa ni ẹni to le ba ọmọde lopọ tabi ko arun ba wọn lasiko arun Covid-19 yii.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Wo igbesẹ ti ijọ Anglican ni Ghana gbe lori isẹlẹ yii

Nigba to di ọjọ Isẹgun ni ijọ naa kede pe ki Fada Balthazar Obeng Larbi lọ rọọkun nile na lẹyin ipade ti awọn alasẹ ijọ ati ile iwe naa se lati tanna wadi ihuwasi rẹ to n fa ariwo naa.

Koda, loju ẹsẹ ni wn ti gba ipo alufa ileẹkọ naa lọwọ Fada yii, ti wọn si tun ni ko ni sisẹ bii amofin mọ fun ẹka eto ẹkọ lorilẹede Ghana fun ẹkun Ashante.

Bakan naa ni ijọ wa kede fawọn araalu pe wọn ti n se idanilẹkọ fun akẹkọbinrin mẹtẹẹta ti ọrọ yii kan.

Àkọlé fídíò,

Ilé wó lu Bisi, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kú, wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ tó ń jẹrà, inú ìrora ló wà ṣùgbọ́n

"A ti ni ki Fada Balthazar Obeng Larbi lọ rọọkun nile na gẹgẹ bii Alufa ileẹkọ olukọni naa, ta si tun ko lọ sinmi lori awọn isẹ miran to n se titi ta fi pari iwadi wa lori awọn ẹsun ti wọn fi kan.

Bakan naa ni igbimọ to n tanna wadi ẹsun alufa naa yoo gbe aba kalẹ lori igbesẹ to kan lori isẹlẹ yii lẹyin iwadi wọn."