Climate change famine: Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ni máa jẹ tata nítorí ìyàn tó mú

Tata tawọn eeyan n jẹ

Oríṣun àwòrán, WFP/TSIORY ANDRIANTSOARANA

Nnkan ko fara rọ mọ lorilẹede Madagascar lẹyin ti iyipada oju ọjọ ti jẹ ki iyan mu nilẹ naa bayii.

Ajọ iṣọkan agbaye, UN ṣalaye pe ẹgbẹẹgbẹru eeyan ni Madagascar ni ebi n pa bayii tori ọwọngogo ounjẹ nibẹ.

Ọwọngogo ounjẹ yii ko ṣẹyin ojo ti ko rọ fun ọdun mẹrin gbako eleyii to ṣakoba nkan ọgbin ni Madasgasacar.

Ọda ojo, eleyii to buru julọ ni ogoji ọdun ni Madadascar ti ṣakoba nla fun ere oko atawọn eeyan eeyan to wa lapa guusu orilẹede naa debi pe tata ni ọpọ eeyan n jẹ bayi.

Alakoso eto ounjẹ fun ajọ UN, Shelley Thakral, ṣalaye pe ki ṣe ija lo fa iyan to mu ni Madagascar bi ko ṣe ayipada oju ọjọ.

Àkọlé fídíò,

Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Ajọ UN sọ pe o kere tan eeyan bii ẹgbẹrun lọna ọgbọn ni ebi n ba finra bayii nibẹ.

Ajọ naa ni awọn eeyan yii yoo si tun pọ si pẹlu bi nnkan ṣe ri.

Àkọlé fídíò,

Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

Thakral ṣalaye pe eleyii ko ṣẹlẹ ri, ayipada oju ọjọ ki ṣe ẹbi awọn eeyan yii to n jiya lọwọ.

Awọn ara abule Fandiova ni ẹkun Amboasary lawọn eeyan ri ti wọn n jẹ ti wọn n wa tata kaakiri lati jẹ.

Iya ọlọmọ mẹrin kan, Tamaria ni oun tawọn ọmọ oun ti n jẹ tata bayii fun oṣu mẹjọ.

Tamaria ni ko si nkan mii tawọn le jẹ mọ nitori ojo ko rọ lati ri nkan oko jẹ.

Àkọlé fídíò,

Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Obinrin mii to bimọ mẹta, Bole ni ewe loku ti oun ati awọn eeyan oun n jẹ bayii.

O ni ọkọ oun ṣẹṣẹ ku laipẹ yii ni nitori ai ri ounjẹ jẹ naa ni

Àkọlé fídíò,

Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell