Afganistan Evacuation: Reach, orúkọ ọkọ̀ òfurufú tíwọ́n bi ọmọ Afganistan ọjọ́si si náà ni wọ́n sọ ọmọbìnrin ọ̀hún

Orúkọ ọkọ̀ òfurufú tíwọ́n bi ọmọ Afganistan si ni wọ́n sọ

Oríṣun àwòrán, US Air mobility command

Wọ́n bí ọmọ kan lójú òfurufú lásìkò tí wọ́n ń dóòlà àwọn ènìyàn kúrò ní Afganistan ni wan ti sọ ni ní orúkọ ọkọ̀ ofurufú

Ọmọbinrin ti wọ́n bí sínú ọkọ̀ òfurufú ilẹ̀ Amẹríkà Ramstein Air base ni Germany ni wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ni Reach èyí tó jẹ́ orúkọ ọkọ̀ òfurufú náà.

Ọ̀gá àgbà ọmogun ilẹ̀ Amẹrika ni Europe, Tod Wolters lo sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn oníròyìn ni Pentagon l'Ọ́jọ́rú.

Ọkọ̀ òfurufú Boeing C-17 ti àwọn ọmọogun ilẹ̀ Amẹrika ti wọ́n mán pè ni Reach nípa lílò àwọn àtopọ̀ nọ́mbà ni wọ́n sọ orúkọ ọmọtun ti wọ́n dóòlà àwọn òbí rl ni Afganistan.

Sáájú ní ẹ̀ka ọmọogun ojú òfurufú ti sọ lójú òpó twitter ni òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá pé obìnrrin kan bi ọmọ sínú ọkọ̀ ofúrufu láti Qatar si Germany ti o sì kú díẹ̀ ki ọ̀rọ̀ yíwọ́.

O ní awakọ̀ òfurufu náà ni láti wá sí ilẹ̀ díẹ̀ láti jẹ́ kí atégun wà fún ẹni to n rọbí èyi si lo fun obìnrin náà lánfàni láti bi ọmọ rẹ̀ láyọ̀, ọmọ àti ìyá sì wà lálàfíà.

Àwọn sójà ló ran obinrin náà lọ́wọ́ ti wọ́n gbẹ̀bi fún nilé ìkẹ́rù sí nínú ọkọ̀ òfurufú ni kété ti wọ́n balẹ̀

Wolter ni àwọn ọmọogun sí n bá àwọn òbí ọmọ náà sọ̀rọ̀ láti àsìkò náà títí di àsìkò yìí.

" Bí mó ṣe jẹ́ ajagun ojú òfurufú, yóò wùmí kí ọmọ ti wọ́n pè ni Reach yìí dàgbà kí ó dí ọmọ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Amẹrika, ki òun pẹ̀lú máá wa ọkọ̀ òfurufú fún àwọn ọmọogun ojú ofurufú" Gẹ́gẹ́ bi Wolter ṣe sọ.