Kabul Airport Attack: Nǹkan ti a mọ̀ nípa ìkọlù tó wáyé ni Kabul

Afganistan Attack: Nǹkan ti a ms nípa ìkọlù tó wáyé ni Kabul

Lọ́sàn òní ni ìbúgbàmù kan dún ni kabul ti ṣe olúùlú Afganista.

Ẹ̀bá ẹnú ìbodè Abbey ti wọ́n ti má n kó àwọn ènìyàn ti wan ń dóòlà lọ sí ill òkèrè ni pápákọ̀ òfurufú Afganistan lẹ́bàá ilé ìtura Baron .

Agbẹnusọ Pentagọn ti fi idi rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Amẹrika àti àwọn ọmọ Afganistabn lo ti jẹ ọlọrun nípè nígbà ti àwọn kan fi ara pa.

Àwòràn fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló wà nílẹ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Amẹrika náà fi kun pé ìró ìbọn náà ń dún lákọlákọ

Ìbúgbàmù náà wáyé ni kété tí ilẹ̀ Amerika àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọ́n láti jìnà sí pápákọ̀ òfurufú, tí wọ́n sì ti sọ fún wọ́n pé ó ṣeeṣe kí àwọn agbésùmọ̀mí ṣọṣẹ́.

Wọ́n ti jábọ̀ fún ààrẹ orilẹ̀-èdè Amẹrika, Joe Biden lórí nǹkan ti ó n ṣẹlẹ̀, bákan náà ni òun pẹ̀lú ń ṣàlàmí nǹkan ti ó n ṣẹlẹ̀ níbẹ̀

Ààrẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Boris Johnson àti Joe Biden ti ilẹ̀ Amẹrika ní yóò jọ jòkó ṣèpàdé láìpẹ́.

Ó kéré tán ènìyàn ọgọ́ta lo ti jẹ́ Ọlọ́run nípè ti àwọn ogóje sì ti ni ìpalára níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ni pápákọ̀ òfurufú gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ètò ilera kan ní Kabul ṣe sọ fún BBC

Pẹntagọn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika to ku níbẹ̀ jẹ òṣìṣẹ́ ìrànwọ́, sùghbọ́ kò tíì sọ iy wọn.

dédé aago mẹ́fà ìrẹ̀lẹ́ ni ìbí gbàmù àkọ́kọ́ niẹ̀bọ́ ilé ìtùra Baron nítòsí pápákọ̀ òfururú.

Tí ìró ìbọ́n sì tèlé, nígbà náà ni ìbúgbàmù kèjì wáyé ní ẹ̀bá ìloro papakọ náà.

Ìròyìn sọ pé, nítòsí, kòtò tí wọ́n ń da ìdọ̀tí sí ni adó olóró kejì ti dún nígbà ti àwọn ènìyàn ń yẹ̀wé wọn wò, nítìrí náà inú kòtò náà ni wọ́n rọ sí

Ọ̀kan nínú òṣìṣẹ́ U.S sọ pé ọkàn nínú àwọn ènìyàn náà ti so àdó olóró mọ́ ara sáájú.

Orílẹ̀-èdè Amerika ati Gẹ́ẹ̀sì tí rà àwọn ọmọ ogun wọn láti lọ sọ agbegbe Abbey Gate.

Gẹ́gẹ́ bi ẹnìkàn ṣe sọ àwọn agbésùmọ̀mí náà ń yìnbọn sí àárín àwọn ènìyàn, sùgbọ́n ìròyìn mííràn tún sọ pé àwọn ọmọoogun Tgaliba naa yìnbọn sínú afẹ́fẹ́.

Ìye ènìyàn tó kú tí n peléke sí ni láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀.

Iye ènìyàn tí ó kú láàrín àwọn ọmọ US àti Afgbanistan to fi mọ àwọn Taliban, ko ti ni iye.