Bathel Baptist Hisgh School: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 32 lára àwọn tó le ní ọgọ́rùn tí wọ́n jí gbé ti gba òmìnira

Patako idanimọ ile ẹkọ girama Bethel

Oríṣun àwòrán, dailytrust

Mejilelọgbọn lara awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama Bethel Baptist High School ti awọn agbebọn gbe salọ nile nipinlẹ Kaduna, ti gba ominira.Wo iye ìgbà tí wọ́n ti jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Nàìjíiríà

Ibẹrẹ oṣu Keje, ọdun 2021, ni wọn ji awọn akẹkọọ naa, to le ni ọgọrun, gbe nile ẹkọ wọn.

Ẹnikan lara awọn olori agbegbe naa sọ fun BBC pe wọn tu awọn ọmọ naa silẹ lẹyin ti wọn san owo fun awọn ajinigbe naa.

Diẹ lara wọn si ti gba ominira ni ọsẹ diẹ sẹyin, ṣugbọn igbagbọ wa pe akẹkọọ to to ọgbọn ṣi wa ni ahamọ.

Ikede tuntun yii waye lẹyin wakati diẹ ti awọn akẹkọọ to le ni ọgọrun, ile Keu ati ile ẹkọ giga imọ eto ọgbin, gba ominira lọwọ ajinigbe.

Awọn amoye gbagbọ pe owo ti awọn eeyan n san fun awọn ajinigbe lo tubọ mu ki ijinigbe o pọ si.

Àkọlé fídíò,

Thyroid foundation: eéwo ni mo kọ́ka pè é àṣé gẹ̀gẹ̀ ọrùn tó lé ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ni mo n

Àwọn òbí ta dúkìá, ilé ẹ̀kọ́ Islamiya ta ilẹ̀ wá N61m owó ìtúsílẹ̀ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Tegina tó gbòmìnira

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ Islamiya to wa niluu Tegina ni ipinlẹ Niger ti gba ominira bayii.

Akẹkọọ mẹrinlogoje lawọn janduku ajinigbe pawo ọhun gbe lọ nile ẹkọ naa.

Mẹẹdogun ninu wọn moribọ lakata awọn ajinigbe loṣu kẹfa, niga ti mẹfa ku sinu igbo.

Owo itusilẹ to le ni miliọnu mọkanlelọgọta naira lawọn janduku ajinigbe pawo ọhun gba ki wọn to fi awọn akẹkọọ naa silẹ.

Awọn obi atawọn alaṣẹ ile ẹkọ naa lo jọ wa owo yii.

Àkọlé fídíò,

Test your Yoruba language skill: Wá ká jọ sọ Yorùbá...

Koda awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ni lati ta lara ilẹ ile ẹkọ ọhun nigba tawọn obi ta dukia wọn lati wa owo san fawọn janduku ajinigbe yii.

Awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa tun fikun pe awọn ajinigbe tun gba alupupu yatọ si owo ti wọn gba.

Àkọlé fídíò,

Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Oru ni wọn fi bọọsi ko awọn ọmọ naa gba ọna inu to wa lẹgbẹ ile ẹkọ wọn lọ.

Ọga ile ẹkọ naa, Abubakar Alhassan sọ fun BBC pe awọn akẹkọọ to bọ lọwọ awọn ajinigbe yii nilo itọju.

Àkọlé fídíò,

Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Alhassan ni o ti rẹ awọn akẹkọọ naa, eyi gan an lo jọ ki wọn gbe wọn lọ si iloe iwosan fun ayẹwo ki wọn to lanfaani lati lọ si ile wọn.

Awọn obi ko le duro mọ lati ri awọn ọmọ wọn pada lẹyin ti wọn ti wa ninu igbo fun oṣu mẹta pẹlu awọn janduku ajinigbe.

O ti le lẹgbẹrun kan akẹkọọ ti wọn jigbe lawọn ile ẹkọ lati oṣu kejila ọdun 2020 si asiko yii.

Ọpọ ninu wọn lo si ti gbominira lẹyin tawọn ajinigbe gba owo itusilẹ.

Àkọlé fídíò,

Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí