Nigeria's debt: Ìjọba Buhari fi N2.02tn san èlé orí gbèsè láàrin oṣù mẹ́fà

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bashir Ahmad

Pekele pekele, arugbo jẹ gbese ta ni o san an.

Ọrọ gbese ti Naijiria jẹ to doju rẹ bayii o. Oludamọran ọga agba ọfiisi eto iṣuna, Alfred Okon lo ja gudugbẹ ọrọ lulẹ nigba to sọ pe owo to le ni tiriliọnu meji naira ni Naijiria fi san ele ori gbese to jẹ

Okon ṣalaye pe ijọba Naijiria san obiti biti owo yii lati oṣu kinni si ikẹfa ọdun 2021.

Ohun to n wa kọ ọpọ onimọ iṣiro owo ninu ni pe owo ohun le ni ida aadọrun ninu ọgọrun owo to wọle fun si apo jọba laarin oṣu mẹfa yii.

O ṣalaye pe N2.23tn ni gbogbo owo to wọlẹ si apo ijọba laarin oṣu kinni ọdun 2021 si oṣu kẹfa eleyii ti ijọba lo 2.02 ninu rẹ lati san ele gbese.

Àkọlé fídíò,

Test your Yoruba language skill: Wá ká jọ sọ Yorùbá...

Ọgbẹni Okon ṣalaye siwaju sii pe N1.3tn ni ijọba gbe jade fun akanṣe iṣẹ lati ibẹrẹ ọdun to fi di oṣu kẹjọ yii.

Ninu ọrọ tiẹ, ọga agba lọfiisi eto iṣuna, Ben Akabueze sọ pe ijọba yoo tete ṣiṣẹ lori eto iṣuna ọdun 2022.

Àkọlé fídíò,

Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Ọgbẹni Akabueze ṣalaye pe gbogbo awọn ẹka ijọba ti ọrọ eto iṣuna kan ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.

O ni ko ni pẹ rara ti ijọba apapọ yoo fi gbe aba iṣuna lọ siwaju ile aṣofin niluu lati buwọlu u.

Akabueze ni eto iṣuna 2022 wa ni ibamu pẹlu eto ti ijọba apapọ n ṣe kaakiri orilẹede Naijiria.