Rachel Oniga burial: Wo bi ètò ìsìnkú gbajúgbajà òṣèré, Rachael Oniga ṣe lọ

Isinku Racheal Oniga

Wọn ti sin oku agba oṣere, Rachael Oniga loni ọjọ Ẹti.

Awọn ọrẹ, ẹbi ati akẹẹgbẹ rẹ lo peju-pesẹ si adugbo Magodo, nipinlẹ Eko, nibi ti eto isinku naa ti waye.

Ọjọ Aje ni ayẹyẹ isin idagbere ti bẹrẹ fun oṣerebinrin naa, pẹlu eto idanilẹkọọ.

Bakan naa, ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ni eto isin orin kikọ waye ni ile ijọsin Aguda, Catholic Church of Resurrection, Magodo, Phase 2.

Ọjọ Ẹti ni wọn tẹ ni itẹ ẹyẹ ni ile ijọsin naa, nibi ti eto isinku ti waye.

Gẹgẹ bi ikede ti ẹbi oloogbe fi sita, awọn ọmọ ati ẹbi nikan ni wọn gba laaye nibi eto isinku naa.

Diẹ niyi lara awọn aworan nibi eto isinku naa: