Yoruba Nation Agitation: Àwọn aláìní nǹkan ṣe lo n pè fún ìyapa Nàìjíríà- Gómìnà Oyetola

Yoruba Nation Agitgation: Àwọn aláìní nǹkan ṣe lo n pè fún ìyapa Nàìjíríà- Gómìnà Oyetola

Oríṣun àwòrán, Oyetola

Gómìnà ìpińlẹ̀ Osun Gboyega Oyetola ti bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó ń pè fún Yorùbá Nation àti Biafra Republic

O ní àwọn tó n ṣe àtilẹyin fún ìpè yìí jẹ́ aláìní ǹnkan ṣe pẹ̀lú.

Lásìkò tó n péjú síbi ètò kan tí ìlé iṣẹ́ ìròyìn NAN gbékalẹ̀ ló tí sọ pé, isọkan orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ṣe kókó jùlọ.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ nínú àtúnṣe ètò ọ̀rọ̀ àjé àti ètò òṣèlú ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ju kí olúkúlùkù lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lọ.

" Ní bí èmi ṣe ròó, mí o faramọ́ kí àwọn ènìyàn lọ lọtọọtọ.Tí a ba tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ àtúntò, sùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọ́n ń ronú sí pínpín Nàìjírià, wọn kò mọ̀ nǹkan ti wọ́n ń ṣe."

"Ìbáṣepọ̀ wá ti jìnà, kárìnkápọ̀ yíyẹ ló ń yẹni ni ó yẹ kí a fi ọ̀rọ̀ náà jẹ́, àti pé tí ifọwọsowọ́pọ̀ bá wà, yóò ran wọ́n láwọ́ láti rí ẹ̀tọ́ wọn gbà."

Gómìnà ní ó sàn kí ìpińlẹ̀ pè fún kí àgbàra ìjọba àpapọ̀ dínkù ju pé kí wọ́n máá pè fún ìyàpa lọ.

" Kí ará ìlú gbárukù ti ìpínlẹ̀, kí ìpinlẹ̀ náà sì máá rí owó tó tó owó gbà láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìlú wọ́n lọ́nà tí ó tọ́ àti tí ó yẹ.