Bread high price: Àlékún bá iye owó búrẹ́dì l'Oṣun, Kwara lẹ́tyìn ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ oníbúrẹ́dì

Owo burẹdi ti lekun ni awọn ipinlẹ kan ni ilẹ Yoruba bi Osun ati Kwara.
Eyi ko si ṣẹyin igbesẹ tawọn apapọ ẹgbẹ oniburedi gbe nipa iyanṣẹlodi ọlọjọ meji ti wọn gun le.
Ababọ iyanṣẹlodi yi ni bi wọn ti ṣe kede afikun iye owo burẹdi lawọn ipinlẹ mejeeji yi.
Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oniburẹdi ni ipinlẹ Osun Alhaji Onaopepo Bakare ati akọwe ẹgbẹ Adeeyo M.A ti ṣalaye, igbesẹ alekun yi waye kawọn baa ṣi le maa ṣ'owo burẹdi tita f'araalu ni.
Wọn ni iyẹfun tawọn fi n ṣe burẹdi ti gbowo lori di ẹgbẹrun lọna mejilelogun Naira.
- Ìwà ìkà gbáà ni gbígba owó orí lóríi Búrẹ́dì- Gómìnà Yahaya Bello
- Ṣé lóòtọ́ ni agbẹjọ́rò DSS wọ ọkọ̀ "One Chance" tàwọn adigunjalè sì jí fáìlì ẹjọ 'Igboho' lọ́wọ́ rẹ̀?
- Wo iye mílíọ̀nù tí Miyetti Allah yóò máa ta màálù kan tí ìpínlẹ̀ Eko bá fòfin de ìdẹranjẹko ní gbangba
- Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré lọ w'òkú wọn
- Alálẹ̀ ló fi èmi àti Sunday Igboho pamọ́ sí àhámọ́ kí ewu le ré wa kọjá - Oba Ogboni
Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn
Yatọ si iyẹfun wọn ni awọn nkan miran tawọn n lo lati fi peelo burẹdi ti lewo.
Lọjọ Ẹti ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi ni Osun ti wọn si fopin sii ni ọjọ Aiku.
Ni bayi, wọn kede pe burẹdi ti wọn n ta ni ọgọrin Naira ti di ọgọfa Naira nigba ti eleyi ti wọn n ta ni ọgọfa Naira ti di aadọjọ Naira.
Buredi ti wọn n ta ni igba Naira ti wa di ojilenigba le mẹwaa Naira.
Alekun to ba iye owo burẹdi ti a ri ni Osun yi jẹyọ ni Ilorin ni ipinlẹ Kwara.
Burẹdi ti wọn n ta ni aadọta Naira ti di ọgọta Naira.
Oni ọgọrun Naira ti di Ọgọfa Naira.
Awọn mii ni burẹdi oni igba Naira to di ojilenigba le mẹwaa Naira bayi.
''Slice bread'' ti wọn n ta ni irinwo Naira ti di ẹẹdẹgbẹta Naira nigba ti eleyi ti wọn n ta ni ẹẹdẹgbẹta Naira si ti di ẹgbẹta Naira.
Ati onibara ati awọn alarobọ burẹdi ti wọn pe sori eto ileeṣẹ redio kan ni Ilorin lo n ke irora lori alekun owo burẹdi yi ti wọn si rọ ijọba lati mu idẹkun ba ara ilu.

Mọ̀ síi nípa Ola Ibironke, Dudu Heritage, ọkọ Bimbo Oshin tó jẹ́ gbajugbaja to n gbé iṣẹ́ olórin síta tó ṣáláìsí
Ikú dóró! Dudu Heritage, olówó orí Bimbo Oshin ti jáde láyé.