Twitter ban: Ó ti pé ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí ìjọba ti f'òfin de Twitter

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, AFP

O ti pe ọgọrun ọjọ bayii ti ijọba orilẹede Naijiria to fi ofin de oju opo ikansira ẹni Twitter.

Amọ awọn ọmọ Naijiria si ti n sọ aidunnu wọn lori bi igbesẹ ijọba orilẹede yii.

Ọjọ kẹrin oṣu kẹfa ọdun 2021 yii ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari kede ifofinde lilo Twitter ni Naijiria.

Lati igba naa ni ijọ ti n gbero lati ri pe awọn ileeṣẹ oju opo ayelujara fi orukọ silẹ lorilẹede Naijiria ki wọn to lanfaani lati maa ṣiṣẹ.

Koda, ọpọ awọn ileeṣẹ iroyin ni lati yọ oju opo Twitter wọn kuro ki wọn maa ba ri ibinu ijọba.

Wọnyii ni nkan mẹfa tawọn eeyan ti padanu lẹyin ti ijọba f'ofin de Twitter

1. Ifọrọjomintoro ọrọ

Lara nkan tawọn eeyan padanu nipa Twitter ni ifọrọjomitoro ọrọ ayelujara.

Nigba kugba ti iṣẹlẹ kan ba ti ṣẹlẹ lawọn maa n bẹrẹ si fọrọ jomitoro ọrọ lori rẹ.

Awọn kan le gba ọrọ kan bi ẹni n gba igba ọti fun ọpọlọpọ wakati titi ti yoo fi rẹ wọn.

2. Ipolowo ọja ara ẹni

Ọpọ ọmọ Naijiria lo maa n ṣe ipolowo ọja tabi iṣẹ ti wọn n ṣe loju opo Twitter.

Ọpọ eeyan lo n ṣe kata kara loju opo Twitter lai tiẹ ri ẹni ti wọn n ba duna dura.

Iru awọn eeyan bayii ti padanu iru anfaani yii ti wọn n ri jẹ lori opo Twitter.

3. Mimọ nipa ọrọ to n lọ kaakiri agbaye

Ọkan lara nkan tawọn eeyan tun padanu nipa aini anfani lati lo Twitter fun bi ọgọrun ọjọ bayii ni mimọ ohun to n lọ lọwọ lagbaaye.

Nibi kibi ni iṣẹlẹ kan tabi omiran ti le maa ṣẹlẹ lagbaaye, lori Twitter lawọn eeyan ti maa n kọkọ gbọ nipa rẹ.

Ileeṣẹ aladani atawọn ileeṣẹ ijọba gan an maa n lo Twitter lati kede igbesẹ wọn fun araye.

4. Fifi ara ẹni ṣe yẹyẹ

Ohun miran tawọn eeyan tun padanu lati igba ti wọn ko ti ri Twitter lo mọ ni fifi awọn eeyan ṣe yẹyẹ.

Ka ni pe ijọba ko tii fofin de oju opo Twitter ni Naijiria lasiko ti Tega ati Boma fi kuro nile Ẹlẹgbọn Agba, BBNaija ni, yẹyẹ ko pọju lori Twitter.

Wọn a maa fi ẹlọmiran ṣe yẹyẹ debi pe o maa ni lati sa kuro lori ẹrọ Twitter.

5. Ofofo

Nkan mii tawọn eeyan tun padanu nipa airi Twitter lo ni ofofo ṣiṣe.

Gbogbo awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ bi ọrọ gbajugbaja oṣere Odunlade Adekola to binu sọrọ pe oun kii beere fun ibalopọ ki oun to lo obin ninu ere.

Ori Twitter ni ọrọ naa ko ba lagbara julọ ka ni pe ijọba ko ti fofin de Twitter ni.

6. Ibadọrẹ pọ

Ohun miran tawọn eeyan ti padanu nipa airi Twitter lo ni ibadọrẹ pọ awọn eeyan.

Ọpọ eeyan lo ni oriṣiiriṣii ọrẹ loju opo Twitter.

Koda, pupọ ninu awọn ọrẹ yii lawọn eeyan kii lanfaani lati ri soju bayii.

Idi niyii ti ọpọ fi n ke si ijọba lati gbẹsẹ kuro lori Twitter kawọn eeyan le ni anfani lati maa lo Twitter bi ti tatẹyin wa.