Ilẹ̀ ń j'ẹ̀nìyàn, ìyá ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀ Florence Ajimobi jáde láyé

Victoria Amudoaghan

Oríṣun àwòrán, Oyo Insight

Victoria Amudoaghan to jẹ iya iyawo gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri, Florence Ajimobi ti dagbere faye.

Gẹgẹ bi iroyin ti o tẹ BBC Yoruba, opin ọsẹ to lọ ni mama jade laye.

Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020 ni Gomina ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi jẹ Ọlọrun nipe ni tiẹ.

Ọmọbibi ipinlẹ Delta ni mama aya gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ti o si tun jẹ ọmọ ijọ Aguda nigba aye rẹ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa lori iṣẹlẹ naa laipẹ.