Boko Haram: Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí UAE ń wá lórí ẹ̀sùn ṣíṣe àtìlẹ́yìn owó fún Boko Haram

Awọn Boko Haram

Oríṣun àwòrán, AFP

Ijọba orilẹede UAE ti kede pe oun n wa ọmọ Naijiria mẹfa to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram.

Awọn mẹfa yii lo wa lara eeyan mejinlogoji ti UAE kede pe awọn n wa lori ẹsun pe wọn n ṣagbatẹru fun igbesunmọmi.

Abdurrahaman Ado Musa, Salihu Yusuf Adamu, Bashir Ali Yusuf, Muhammed Ibrahim Isa, Ibrahim Ali Alhassan ati Surajo Abubakar Muhammad ni awọn ọmọ Naijiria mẹfa ọhun.

Iroyin sọ pe ni nkan bi ọdun kan sẹyin ni orilẹede UAE kede pe awọn ọmọ Naijiria naa n ṣe atilẹyin fun Boko Haram.

Awọn ọmọ orilẹede mii ti ilẹ UAE n wa ni Ahmed Mohammed Abdulla Mohammed Alshaiba Alnuaimi (UAE), Mohamed Saqer Yousif Saqer Al Zaabi (UAE), Hamad Mohammed Rahmah Humaid Alshamsi (UAE), Saeed Naser Saeed Naser Alteneiji (UAE) pẹlu Hassan Hussain Tabaja (Lebanon).

Awọn miran tun ni Adham Hussain Tabaja (Lebanon), Mohammed Ahmed Musaed Saeed (Yemen), Hayder Habeeb Ali (Iraq), Basim Yousuf Hussein Alshaghanbi (Iraq) ati Sharif Ahmed Sharif Ba Alawi (Yemen).

Ileeṣẹ iroyin kan lati UAE ṣalaye pe ijọba gbe orukọ awọn eeyan yii jade gẹgẹ bi ọkan lara ọna lati bi dẹkun awọn eeyan to n ṣagbatẹru igbesunmọmi.

Ẹwẹ, ile ẹjọ giga Abu Dhabi dajọ ẹwọn gbere fun ọmọ Naijiria meji, Surajo Abubakar Muhammad ati Saliuh Yusuf Adamu.

Bakan naa tun ni ile ẹjọ ni ki wọn fi orilẹede naa silẹ.

Ile ẹjọ dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa fun Ibrahim Ali Alhassan, AbdurRahman Ado Musa, Bashir Ali Yusuf ati Muhammad Ibrahim Isa, to si tun sọ pe ki wọn fi orilẹede UAE silẹ.

Ile ẹjọ tun ni wọn jẹbi ẹsun dida ọgba ẹwọn Boko Haram silẹ.

Awọn eeyan yii ni wọn ni wọn fi owo to to $800,000 ṣe atilẹyin fun Boko Haram laarin ọdun 2015 si 2016.