Poor roads in Ekiti state: Femi: Ká yọ tòṣèlú kúrò, Fayemi, àwọn òpópónà Ekiti ti di ẹgẹrẹmìtì, Babafemi Ojudu làá mọ́ Gómìnà Fayemi

Fayemi ati Ojudu

Oríṣun àwòrán, other

Ọrọ oṣelu nipinlẹ Ekiti tun ba ibomiran yọ pẹlu bi o ṣe fẹ jọ pe, awọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa meji ti n ta si ara wọn bayii.

Kayọde Fayẹmi ni gomina ipinlẹ Ekiti, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni. Ọkan lara awọn to jẹ aṣiwaju lagbo oṣelu ni Babafẹmi Ojudu jẹ, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC naa ni.

Ireti ọpọlọpọ onwoye ni pe o yẹ ki ọrọ awọn mejeeji ye ara wọn, amọṣa eyi ko fẹ da bi ẹni pe o n ri bẹẹ lọwọ.

Atẹjade kan ti Ọgbẹni Fẹmi Ojudu fi sita lọjọ Iṣẹgun lo ti n wọ Gomina Kayọde Fayẹmi atijọba rẹ pe wọn ko karamasiki ipo awobọkanjẹ tawọn opopona to wa ni ipinlẹ naa wa.

Àkọlé fídíò,

Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Ninu atẹjade naa, Ọgbẹni Ojudu ni oun ko lee dakẹ bi o tilẹ jẹ pe awọn kan lee maa ṣi ọrọ oun tumọ loun fi n pariwo lati pe akiyesi gomina Kayọde Fayẹmi ati ijọba rẹ si ipo arigbarimu ti awọn opopona wa ni ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Femi ni: "Ipo ti awọn opopona ni ipinlẹ Ekiti wa n ba eeyan lọkan jẹ. Mo wa nibẹ lopin ọsẹ to kọja n ko si fẹrẹ lee gba ohun ti oju mi n ri gbọ. Gbogbo opopona igboro ati awọn ti marosẹ to wọle tabi jade ni ipinlẹ naa ni wọn ti di ẹgẹrẹmiti.

Àkọlé fídíò,

Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Ojudu fi kun un pe asiko to ki Gomina Fayẹmi o kede aṣẹ nnkan o fara rọ lẹka ipese ohun amayedẹrun ni ipinlẹ naa lati lee tubọ mojuto ẹka naa nitori pe iṣoro ati idojukọ tawọn olugbe ipinlẹ Ekiti maa n dojukọ bi ojo ba tun wa rọ lawọn ọna naa kii ṣe kekere.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation