Sunday Igboho trials in Benin Republic: Sunday Igboho ké sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti dáríji agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic

aworan Amofin Salami, iwaju ile ẹjọ ni Benin Republic ati aworan Oloye Igboho

Oríṣun àwòrán, other

Aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti ke sawọn ọmọ Yoruba to wa lẹyin ijijagbara to n lepa pe ki wọn foriji ọkan lara awọn agbẹjọro to n gbọ ẹjọ rẹ ro lorilẹede Benin Republic, Amofin Ibrahim Salami.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ diẹ sẹyin ni oloye Sunday Igboho ti fi ibinu rẹ han ninu fọnran ohun kan to lu ori ayelujara ja pe oun ko mọ iṣẹ tawọn lọya naa n ṣe ti oun fi di ẹni to n pẹ lẹwọn lorilẹede Benin Republic fun nnkan bii aadọta ọdun.

Ọkan lara awọn agbodegba fun Oloye Igboho, Aarẹ, Almaroof Bọbagunwa Yẹkini ninu fidio kan to fi sori ayelujara ti wa ṣalaye pe oun ati Oloye Sunday Igboho ti pada sọrọ lẹyin edeaiyede naa, o si ti rọ gbogbo awọn ololufẹ ijijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba pe ki wọn darijin agbẹjọro Salami.

"O ni ki gbogbo awọn ajijagbara atawọn to pariwo rẹ kaakiri o darijin. A nilo rẹ, oun naa si nilo wa, a jijọ nilo ara wa ni."

Aarẹ Bọbagunwa Yẹkini to ṣapejuwe Igboho gẹgẹbi "oriṣa ni Naijiria, akinkanju jagunkagun" ti kii fi iwọsi lọ ẹnikẹni ṣalaye pe Igboho ko korira Amofin Salami atawọn ikọ agbẹjọwro ti wọn jumọ n ṣiṣẹ lori ẹjọ rẹ lorilẹede Benin, nitori naa ki wọn tete gbe awsn igbesẹ gbogbo fun ẹjọ naa lati tubọ mu esi to tọ jade.