Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamu-ṣamu.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọdọbinrin Zulfah Abdulazzes to si n lo iboju tawọn ẹlẹsin musulumi tawọn mọ si Hijab.

Amọ eyi mu ki Zulfah da yatọ lori papa gẹgẹ niwọn igba to jẹ pe isẹ bọọlu gbigba fawọn obinrin lo yan laayo.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọmọdebinrin naa ni ọmọ ọdun kan ati aabọ ni oun ti n gbe lọdọ iya oun agba, ki onitọun to jade laye lọdun 2017.

Akẹkọọbinrin agbabọọlu naa ni igbe aye le diẹ fun oun amọ afojusun oun ni pe lọjọ iwaju, ki oun di obinrin agbabọọlu to pegede julọ bii Azzezat Oshoala.

Amọ ti ko ba si lori papa lati gba bọọlu, obi, orogbo ati suti ni Zulfah maa n ta labẹ afara Ojota, ko le ri ọwọ mu lọ si ẹnu.

O wa salaye ọpọ ipenija to n koju lati awọn akẹẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to n lo Hijab.