Akinyele Army Shooting: Àwọn olùgbé Akinyele figbe ta lórí ọ̀pọ̀ ọta ìbọn ológun tó ń wọnú ilé wọn

Ọta ibọn ologun

Lati ọjọ mẹta ni awọn ara agbegbe Omilabu ni ijọba ibilẹ Akinyele ni ilu Ibadan ti n kojú yinyin ibọn loore-koore lati ọwọ awọn ọmọ ogun to wa ni Odogbo.

Adugbo Omilabu to paala pẹlu ibudo awọn ọmọ ogun ni Odogbo, Ojoo ni ilu Ibadan, ni ọta ibọn yinyin awọn ologun naa maa n rekọja si ati awọn adugbo to tun sun mọ.

Awọn aladugbo naa, to fi ẹdun ọkan wọn han lori ayelujara lo mu ki BBC Yoruba se abẹwo sibẹ lati wadi ohun gbogbo daju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko abẹwo BBC si adugbo Omilabu naa, a gbọ pe isẹlẹ naa ko sẹsẹ maa waye, o si ti le ni ọpọ ọdun sẹyin ti wọn ti maa n gbalejo ọta ibọn awọ̀n ologun naa ninu yara wọn.

Alagba kan ni adugbo ọhun to ba ikọ BBC Yoruba sọrọ wi pe ọrọ naa ti wa ní ile ẹjọ nitori ko si iyipada lati ọdọ awọn ọmọ ologun, lẹyin ti awọn lọ parọwa fun wọn.

Awọn baba onile naa, ti wọn ko ogunlọgọ ọta ibọn to gba orule wọ yara wọn jade salaye pe, inu ewu ni awọn n sun, inu ewu si ni awọ̀n n ji si, igbakuugba si ni ọta ibọn le sere de ọdọ awọn.

"Ibọn ti a wi ti ba ọpọlọpọ eniyan, o ti ba orule jẹ pupọ. Ti ẹ ba ni suuru diẹ, ẹ gbọ iro ibọn naa"

"Nigba ti a se iwọde lo ba wọn, wọn fi da wa loju pe yoo dinku amọ ko si iyipada.

"Ati ke si ijọba lati wa gba wa lọwọ ojo ọta ibọn naa, ko si wa nnkan se si ṣugbọn ko si iyipada kankan, ko da gan lọwọlọwọ bayii, wọn si n yin ibọn sita"

"Ọpọlọpọ awọn ara adugbo ni wọn maa n sa wọle ti ibọn ba ti n dun leralera, o si ti se ijamba fun ọpọlọpọ eeyan."

"Akẹkọọ kan ni ibọn ba nile iwe kan to wa ladugbo yii, nibi to ti n sere ni ita, ti a pariwo sita, ko pẹ tun ni ibọn ba alaboyun, ile wosan awọn arabi naa ni a ru wọn lọ. "

Ni pari, Alagba naa ni awon ko si ni ori ilẹ awọn ologun, ti ẹri si wa ti awon ti mu lọ si ile ẹjọ."

Ki akọroyin BBC Yoruba si to pari ifọrọwanilẹnuwo to n se, lojiji lo n gbọ iro ọta ibọn nitootọ, to n dun lakọlakọ, ni akọroyin wa ba juba ehoro, to si sa asala si bibikan lati doola ẹmi rẹ.

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́