Ọmọ ẹgbẹ́ márùn ún lọ́dún mẹ́rin, Kí ló ń fa ikú ọ̀wọọ̀wọ́ lẹ́yìn Davido?

Daavido

Oríṣun àwòrán, Instagram/Davido

Lagbo amuludun lọwọ yii, eeyan lee sọ pe nnkan ko fi bẹẹ fara rọ fun gbajumọ olorin David Adeleke ti ọpọlọpọ mọ si Davido.

Eyi ko seyin ariwo pe iku to n mu awọn eeyan lọ lagbo rẹ lati nnkan bi ọdun diẹ sẹyin.

Ọpọ awọn ololufẹ rẹ ni wọn ti n kọminu lori ipa ti iku awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ wọnyi lee ni lara rẹ; ti awọn kan si n ba a gbadura ki Eduwa ba a dawọ ibi duro.

Awọn ọrẹ ti gbajumọ olorin naa to ti padanu laarin ọdun mẹrin pọ diẹ.

Oun pẹlu si ti fi ara rẹ si abẹ iṣọra lẹyin ti pasitọ kan sọ asọtẹlẹ bi osu kẹfa, ọdun 2021 pe ọrẹ rẹ kan yoo fi majele sinu ounjẹ fun un jẹ.

Davido naa si ti fesi nigba naa loju opo ayelujara pe " Ọlọrun yoo tu aṣiri awọn ẹni buburu to yi mi ka atawọn to jinna si mi. Amin."

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Eyi ni ọmọ ẹgbẹ orin Davido to ti jade laye laarin ọdun mẹrin:

1.Fortunate Ateumunname.

Fortune ni ọpọlọpọ eeyan n pe apeja oruko ree.

Oun si ni ayaworan agba fun ileeṣẹ agborinjade Davido Music World (DMW).

Oṣu kẹsan an, Ọdun 2021 lo ku.

Oun si ni ọmọ ẹgbẹ Davido karun un ti yoo jade laye laarin ọdun mẹrin lọna to n fa ọpọ awuyewuye bayii.

2.Uthman, ti awọn eeyan mọ si Obama DMW:

Uthman ku ni osu kẹfa ọdun 2021. Iroyin sọ pe ariwo irora eemi lo pa ki o to jade laye.

Àkọlé fídíò,

Ayo Ewebiyi Mama Oriki: Ọwọ́ Òbí, Ìjọba àti àwọn Ọba ni ìdágbàsókè Yorùbá wà lásìkò yìí

3. Tagbo Umeike:

Inu ọkọ rẹ lo ku si niwaju ileewosan nla Lagos Island General Hospital.

Ọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi tẹ lo jade laye lọdun 2017.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

4. Olu Abiodun:

Orukọ inagijẹ ti wọn tun maa n pe e ni DJ Olu nigba aye rẹ.

DJ Olu naa jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹyin Davido to ku laarin ọdun mẹrin sẹyin bayii.

5. Tijani Ọlamilekan:

Inagijẹ rẹ njẹ Teejay.

Oun si ni ẹṣọ to n ṣọ gbajumọ olorin naa nigba aye rẹ.

Ọdun mọkanla lo fi ṣọ Davido ki o to jade laye ni oṣu kejila, ọdun 2020.