Anti Open Grazing Law: Àwọn èèyàn gúúsù ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ padà sí El-Rufai lórí àtakò òfin

Darandaran ati maalu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alaga awọn gomina apá guusu Naijiria, Rotimi Akeredolu ti koro oju sí gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai lori bi o ṣe tako fifi ofin de idẹranjẹko lẹkun guusu.

Akeredolu ni ọgbọn ati ko awọn janduku ajínigbé wọ apá guusu ni El-Rufai ń da.

El-Rufai ti kọkọ tabuku bi awọn ipinlẹ apá guusu ṣe ṣ'agbekalẹ ofin tó dé idẹranjẹko ni gbangba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àmọ́, Akeredolu sọ ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnna eto iroyin nipinlẹ Ondo fi sita pe iru ẹni to ba sọrọ ti El-Rufai sọ ko yẹ nipo olori.

Gomina ipinlẹ Ondo sọ pe El-Rufai ń wa ọna lati ko awọn janduku ajinigbe pawo afẹmi ṣofo lọ si ibo miran lẹyìn awọn ologun ti n fina mọ wọn bayii lapa Ariwa Naijiria.

Akeredolu fikun ọrọ rẹ pé irú ọrọ ti El-Rufai sọ yìí lè dá rogbodiyan silẹ laarin ilu.

Àkọlé fídíò,

Ondo School Without Chairs: Iléèwé kan rèé tí kò ní àga, tábìlì, olùkọ́, èlò ìkẹ́kọ̀ọ́

Gomina ipinlẹ Ondo ni fifi ẹran jẹko káàkiri ilu ti di eewọ bayii lapa guusu Naijiria, kò sì sí ohun tí ẹnikẹni le ṣe sí ọrọ naa.

Akeredolu ni awọn ti ko dun mọ kí wọn lọ fọwọ wọnu nitori aṣẹ ti gùn ofin tó dé idẹranjẹko ni gbangba lapa guusu Naijiria.

Ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ agbébọn Boko Haram ló ti jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀- Iléeṣẹ́ ológun

Oríṣun àwòrán, Facebook/NigerianArmy

Ọgagun agba ọwọ keje ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, Ọgagun Abdulwahab Eyitayọ ni ẹgbẹrun mẹjọ lawọn ọmọogun agbesunmọmi Boko Haram to ti jọwọ ara wọn fun awọn ologun bayii.

O ni awọn agbebọn naa jọwọ ara wọn sílẹ lati inu ibuba wọn ni igno Sambisa atawọn ibuba miran.

Ọgagun Eyitayọ to tun jẹ ọgagun agba igun kini, Sector 1 Operaton Hadin Kai ṣalaye eyi lasiko to n gnalejo alukoro ileeṣẹ omogun oriilẹ ni Naijiria, ogagun Onyema Nwachukwu atawọn akọroyin lalejo nilu Maiduguri.

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Ogagun naa ni ohun ayọ ni bi awọn agbebọn naa ṣe n jọwọ ara wọn silẹ ati pe bi awọn ologun ṣe n kona mọ wọn lo n ti wọn sita.

Ọgagun Eyitayọ fi kun pe lọpọ yanturu lawọn agbebõn Boko Haram n jọwọ ara wọn sílẹ lati igba tawọn ọmọ ogun ṣina ibọn fun wọn.

Ogagun naa ni pupọ awọn agbebọn naa lo jẹ pe igbaye gbadun awọn ẹbi wọn lo ṣokunfa bi wọn ṣe darapọ mọ awọn agbebọn naa.

O wa sekilọ pe eyikeyi awọn agbebọn naa ti ko baa jọwọ ara rẹ silẹ ki gbendeke ọjọ ti wọn fi silẹ fun wọn, yoo jẹ iyan rẹ niṣu ti ko si ni yọ awọn agbodegba ati baba isalẹ wọn pẹlu silẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/NigerianArmy

Ọgagun Eyitayọ to tun jẹ ọgagun agba igun kini, Sector 1 Operaton Hadin Kai ṣalaye eyi lasiko to n gnalejo alukoro ileeṣẹ omogun oriilẹ ni Naijiria, ogagun Onyema Nwachukwu atawọn akọroyin lalejo nilu Maiduguri.