AMCON 4.6Billion Debt: Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara tẹ́lẹ̀ sọ́rọ́ nípa nkán ìní rẹ̀ tí Amcon gbẹ́sẹ̀lé

Aworan Gomina tẹlẹ Abdulfatai Ahmed

Gomina ipinlẹ Kwara tẹl ri Abdulfatai Ahmed ti fesi lori fnran fidio to ṣafihan bi ajọ to n mojuto nkan ini Naijiria AMCON ṣe gbẹsẹ le dukia rẹ.

Lọjọru ni fidio kan gba oju opo ayelujara nibi ti agbẹjọro kan to ni oun n ba AMCON ṣiṣẹ ti sọ pe awọn wa lati fofin gba dukia Gomina tẹlẹ Ahmed.

Ninu fidio naa o sọ pe ileẹjọ fawọn laṣ lati gba ile naa to wa ni GRA nilu Ilorin nitori gbese ti ileeṣẹ Fati Ahmed jẹ ijọba.

Agbẹnusọ Gomina tẹlẹ Ahmed, Abdulwahab Oba sọ ninu atẹjade kan pe ijiroro n lọ lọwọ pẹlu Amcon lori gbese yi.

Nitori naa o ni ko bojumu bi Amcon ti ṣe digun lọ gba dukia naa ti wọn si kede rẹ faye gbọ.

Ninu alaye to fi sita, Ahmed ni aigboraẹniye waye latari owo kan toun ya lọdọ awọn banki meji kan ti wọn wa da papọ mọ awọn owo mii tawọn ẹlomiran ya.

O ni o yẹ ki AMCON ta ipin idokowo tawọn ile ifowopamọ yi gba kalẹ ni bi oun ko ba ri owo san pada.

O ni lọwọ lọwọ awọn n jiroro pẹlu AMCON lati yanju ọrọ yi.

O ni o ṣeni laanu pe agbẹjọro to sọrọ ninu fidio yi mọ ibi tọrọ de duro ṣugbọn o ṣe aṣeju nipa pipariwo ọrọ naa sita.