Ethiopia War: Kí ló ń ṣẹlẹ ní Ethiopia tí ìrọkẹkẹ ogun fi gbalẹ níbẹ?

Awọn ọmọ ogun Ethiopia

Oríṣun àwòrán, AFP

Ijọba orilẹede Ethiopia ti se agbekalẹ ofin ilu ko fara rọ yika tibu tooro orilẹede naa lọjọ Isẹgun nitori irọkẹkẹ ogun to gbalk kan ni ariwa orilẹede naa.

Ijọba ti wa n kede fun awọn eeyan to n gbe ni olu ilu orilẹede naa, Addiss Ababa pe ki wọn dihamọra pẹlu ohun ija lati fi daabo bo ara wọn.

Eyi ri bẹẹ nitori bi awọn ikọ ogun ọlọtẹ lapa ariwa ẹkun Tigray se n sun mọ ẹkun guusu orilẹede naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Arọwa yii lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti ikọ ọlọtẹ Tigray People's Front (TPLF) se kede pe oun ti gba akoso ilu nla meji to to irinwo kilomita si Addis Ababa.

Amọ ijọba ilẹ Amẹrika ti n rawọ ẹbẹ si ikọ ọlọtẹ naa pe ko mase gba akoso Addis Ababa nitori awọn eeyan to n gbe nibẹ le ni miliọnu marun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wahala lo n waye laarin ijọba Ethiopia atawọn ọmọ ogun Tigray lẹkun ariwa lo n gbena woju ara wọn, eyi to ti da orilẹede naa sinu rogbodiyan nla.

Ogun naa si ti bẹrẹ ni bi ọdun kan sẹyin lapa ẹkun ariwa Ethiopia.

Nibayi naa, ijọba ilẹ Amẹrika ti wa n ke si awọn ọmọ orilẹede rẹ lati fi orilẹede Ethiopia silẹ ni kiakia.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà