U.I Graduation: Fásitì Ibadan sé ìlẹ̀kún mọ́ ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́jáde àti òbí wọn lásìkò ìkẹ́kọ̀ọ́jáde

Awọn akkọ fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, Advance U.I

Ninu awọn ọjọ moriwu, ọjọ manigbagbe ati ọjọ ayẹyẹ ti ẹda kan maa n fi oju sọna fun ni ọjọ ti eeyan ba gba oye ikẹkọjade nile ẹks giga fasiti.

Saaju ikẹkọgboye, ni obi yoo ti na owo ati ara lati ri pe ọmọ rẹ se aseyege ninu imọ ẹkọ to yan laayo, ti akẹkọọ naa yoo si tiraka pẹlu ara ati ọpọlọ lati mase ja awọn obi rẹ kulẹ.

Bakan naa ni yoo fi oju sọna lọjọ ti yoo di ominira, ti yoo gba paali iwe ẹri moyege kuro ni fasiti, to si di akọsẹmọsẹ nidi ẹka imọ eto ẹkọ to ka fun ọdun mẹrin, marun tabi meje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni obi yoo maa ro ọjọ ti ọmọ oun yoo kẹkọjade, ti wọn yoo gẹ fila ati gele, fi ile pọn ọti, fi ọna ro ọka, ti yoo si ya fọto tikatika pẹlu ọmọ rẹ to n kẹkọ jade.

Ni ọdun 2020 ti arun Coronavirus lu agbaye ka, ọpọ fasiti ni ko seto ayẹyẹ ikẹkọjade fawọn akẹkọjade rẹ nitori bi ọwọja arun naa se n gbilẹ si, ninu eyi ti fasiti Ibadan wa lara wọn.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà

Amọ iyalẹnu lo tun jẹ lọdun 2021 yii nigba tile ẹkọ fasiti Ibadan tun fi ikede kan sita lọjọru, ọjọ Kẹta osu Kọkanla pe isọri awọn akẹkọ to ba gba oye imọ ijinlẹ onipo kinni nikan ni ko yọju fun ayẹyẹ ikẹkọjade lọgba ile ẹkọ naa.

Nibi ayẹyẹ ikọkọjade naa, ti yoo waye laarin ọjọ Kẹẹdogun si Ikẹtadinlogun osu kọkanla ọdun 2021 ni fasiti Ibadan ti ni oun ko fẹ kofiri awọn akẹkọ yoku ati obi wọn nibi ayẹyẹ ikẹkọjade naa.

Atẹjade kan ti alukoro fun fasiti Ibadan, Olatunji Oladejo fisita ni ile ẹkọ giga naa gbe igbesẹ ọhun lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus ni.

Atẹjade naa wa fikun pe gbogbo akẹkọ to n kẹkọjade nile ẹkọ giga naa lo gbọdọ san gbogbo owo to ba yẹ patapata, boya wọn wa se ayẹyẹ ikẹkọjade ni tabi bẹẹkọ.

O ni ile ẹkọ naa yoo duro de wọn lati gba owo yii ni kete ti wọn ba yọju lati wa gba iwe ẹri wọn.

Àkọlé fídíò,

Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53

Lakotan, atẹjade ọhun wa n rọ awọn akẹkọjade ati awọn obi wọn to n bọ fun ayẹyẹ ikẹkọjade lati tẹle awsn ilana to n dena arun Coronavirus.

Bakan naa ni wọn rọ awọn akẹkọjade yoku ti ko jẹ onipo kinni lati lọ soju opo ayelujara, maa kopa nibi ayẹyk ikẹkọjade naa.