Anambra 2021 Election: Wo àkọsílẹ̀ nípa ìtan ayé àwọn oludìbò gómìnà Anambra

Awọn ẹgbẹ oselu to n dije

Fun ọpọ ẹyin ti ẹ ko mọ ohunkohun nipa awọn eeyan to n dije fun ipo gomina nipinlẹ Anambra.

Ẹ wa ka iroyin yii lati mọ nipa oludije mejila to n du aga gomina nipinlẹ́ Anambra mọ ara wọn lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ wa mọ atimaasebọ wọn, ilu ti wọn ti wa, isẹ ti wn n se tẹlẹ, ọjọ ori wọn ati ẹgbẹ oselu ti wọn n dije labẹ rẹ.

Awọn Oludije sipo Gomina nipinlẹ Anambra

  • Isẹ oojọ: Oniṣegun oyinbo
  • Ọjọ ori: Ọdun mejilelọgọta
  • Ilu Umuchukwu nijọba ibilẹ Orumba nipinlẹ Anambra ni Godwin Maduka ti wa
  • O kawe, to si n sisẹ nilẹ Amẹrika, ko to wa darapọ mọ idije fun ipo gomina nipinlẹ Anambra.
  • Isẹ Oojọ: Olusiro Owo
  • Ọjọ ori: Ọdun mejidinlọgọta -Etiaba Bennet Chukwuogo di oludije labẹ asia ẹgbẹ AA lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ oselu APC losu Keje ọdun 2021. -Ilu Ezekwuabor ni otolo-Nnewi lo ti wa. -Oun ni ọmọkunrin to dagba ju laarin awọn ọmọ gomina obinrin akọkọ ni Naijiria, Dame Virgy Etiaba -Oun naa si ni alaga ibudo fawọn akọsẹmọsẹ onimọ olusisro owo fun ẹkun United Kingdom laarin ọdun 2002 si 2004.
  • Isẹ oojọ: Olokoowo
  • Ọjọ ori: Ọdun marundinlọgọta
  • Nwankwo Wilson Chidozie wa lati ilu Oko nijọba ibilẹ ariwa Orumba.
  • O di oludije labẹ asia ẹgbẹ oselu AAC lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ oselu APC tori bo se kuna lati gba tikẹẹti dije fun ipo gomina losu Kẹsan-an ọdun 2021.
  • Olokoowo nla ni, to si maa n dokowo ninu tita awọn eroja ikọle kaakiri orilẹede Naijiria ati iwọ oorun Afirika.
  • Isẹ Oojọ: Oloselu
  • Ọjọ Ori: Ọdun mọkandinlọgọta
  • Akachukwu Sullivan Nwankpo wa lati ilu Okija, nijọba ibilẹ Ihiala nipinlẹ Anambra.
  • O ti sisẹ bii oludamọran pataki fawọn ohun to se koko labẹ akoso aarẹ Goodluck Jonathan. -O si jẹ oludije labẹ ẹgbẹ oselu APGA tẹlẹ, ko to wa sinu ẹgbẹ oselu ADC.
  • Ọjọ ori: Ọdun mọkanlelogun
  • Ilu Amichi nijọba ibilẹ guusu Nnewi lo ti wa
  • O sisẹ bii olori igun ọdọ to n ti aarẹ ana, Goodluck Jonathan lẹyin nipinlẹ Anambra lasiko eto idibo apapọ fọdun 2015.
  • O tun jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn osisẹ elepo rọbi ati afẹfẹ gaasi nilẹ wa, NUPENG.
  • Isẹ Oojọ: Akọsẹmọsẹ adojutofo ni ẹka eto ilera ati oloselu
  • Ọjọ Ori: Ọdun mejilelọgọta
  • Emmanuel Andy Nnamdi Uba ti jẹ gomina ipinlẹ Anambra ri fun ọjọ mẹtadinlogun ldun 2007 ko to di pe ile ẹjọ to ga julọ yọ kuro nipo, ti Peter Obi si gba ipo rẹ.
  • O ti jẹ amugbalẹgbẹ ri fun akanse isẹ ati ọrọ abẹle fun aarẹ tẹlẹ, Olusegun Obasanjo.
  • Ilu Uga, nijọba ibilẹ Aguata nipinlẹ Anambra nii se.
  • Isẹ oojọ: Onimọ nipa ọrọ
  • Ọjọ ori: dun mọkalelọgọta
  • Charles Chukwuma Soludo ti jẹ gomina gomina banki apapọ ilẹ wa ri laarin ọdun 2004 si 2009.
  • Igba akọkọ ree ti yoo gbiyanju lati dije fun ipo gomina nipinlẹ Anambra. Ldun 2010, o fidi rẹmi lasiko to wa labẹ ẹgbẹ oselu PDP, ti Peter Obi si jawe olubori. O tun gbiyanju lati dije dupo gomina lọdun 2013 labẹ ẹgbẹ oselu APGA amọ igbimọ to n sayẹwo oludije ninu ẹgbẹ oselu naa ja kulẹ.
  • Ilu Isuofia nijọba ibilẹ Aguata lo ti wa.
  • Isẹ oojọ: Ajagunfẹyinti ati ayaworan ile
  • Ọjọ ori: Ọdun mẹtalelọgọta
  • Ajagunfẹyinti Geoffrey Okwudili Onyejegbu wa lati ilu Ekwusigo nijọba ibilẹ Anambra
  • Lọdun 2010, o dije fun ipo gomina nipinlẹ Anambra, to si tun dije fun ipo ijoko asofin agba lẹkun guusu Anambra lọdun 2018 amọ ti ko wọle.
  • Isẹ oojọ: Onimọ nipa ihuwasi ẹda
  • Ọjọ Ori: Aadọta ọdun
  • Ilu Umuokpu nijọba ibilẹ Awka lo ti wa.
  • Oun si ni igbakeji alaga fun ile ẹkọ Immaculate Conception (CICOBA) to wa nilu Enugu
  • Isẹ Oojọ: Onimọ Ẹrọ ati ontẹwe
  • Ọjọ ori: Mẹtadinlaadọta
  • Chika Jerry Okeke ti kọkọ dije fun ipo gomina ipinlẹ Anambra laarin ọdun 2013 ati 2017.
  • O dije du ipo ijoko nile asoju-sofin laarin ọdun 2015 ati ipo ijoko ile asofin ipinlẹ Anambra lọdun 2019 amọ to ja kulẹ ni igba mejeeji.
  • Ilu Ezinifite, nijọba ibilẹ Aguata lo ti wa.
  • Isẹ Oojọ: Osisẹ Banki ati olusiro owo
  • Ọjọ ori: Ogoji ọdun
  • Ilu Ezinifite nijọba ibilẹ guusu Nnewi lo ti wa.
  • Isẹ Oojọ: Olokoowo
  • Ọjọ Ori: Aadọta ọdun
  • Ilu Okija nijọba ibilẹ Ihiala lo ti wa.
  • Isẹ Oojọ: Onimọ nipa katakara ilẹ ati ile, Alakoso okoowo
  • Ọjọ ori: Marundinlaadọta
  • Afamefuna Victor Ezenwafor jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ oselu APC fun ijoko ile asofin ipinlẹ naa lẹkun idibo Aguata Keji lọdun 2019 amọ to kuna lati wle ibo naa. O wa lọ sinu ẹgbẹ oselu NRM losu kẹta ọdun 2021.
  • Ọmọbibi ilu Ekwulobia, nijọba ibilẹ Aguata nipinlẹ Anambra nii se
  • Isẹ oojọ: Akọsẹmọsẹ olokoowo
  • Ẹni aadọta ọdun
  • Ilu Amesi, nijọba ibilẹ Aguata lo ti wa
  • Valentine Ozigbo ti sisẹ ri lẹka ifowopamọ ati igbalejo nile itura
  • Oun to jẹ logun bayii ni lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Anambra gẹgẹ bo ti se nidi mimu awọn isẹ idagbasoke kan ba ọpọ agbegbe yika Naijiria. He is passionate about bringing development as he is responsible for some developmental projects around Nigeria
  • Isẹ Oojọ: Onimọ nipa aṣa ibilẹ
  • Ọjọ ori: Ọdun marundinlaadọta
  • Nwawuo ti ọpọ eeyan mọ si Igwe Ayaya, lo gbiyanju lati du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu AA, ko to lọ sinu ẹgbẹ oselu PRP.
  • Ilu Nando, nijọba ibilẹ ila oorun Anambra lo ti wa.
  • Isẹ Oojọ: Agbẹjọro
  • Ọjọ ori: Ẹni ọdun mejidinlọgọta
  • Uzoh Obinna Chukwudum Godwin du ipo gomina labẹ ẹ́gbẹ oselu NDP lọdun 2003. Bakan naa lo tun lakaka lati du ipo yii kan naa lọdun 2013, to si kuna lati gba asia ẹgbẹ oselu PDP gẹgẹ bii oludije wọn, o tun du ipo yii lẹẹkan si lọdun 2017 labẹ ẹgbẹ oselu 2017 amọ to kuna lati gba tikẹẹti oludije labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.
  • Ilu Umunnamehi, nijọba ibilẹ Ihiala nipinlẹ Anambra lo ti wa.
  • Isẹ Oojọ: Akọsẹmọsẹ olokoowo
  • Ifeanyi Patrick Ubah dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu LP amọ to kuna lọdun 2014. Ldun 2019, o dije, to si bori ninu ibo si ijoko ile asofin agba fun ẹkun idibo guusu Anambra labẹ asia ẹgbẹ oselu YPP.
  • Ilu Umuanuka ni Otolo, nijọba ibilẹ Ariwa Nnewi lo ti wa.
  • Ọjọ ori: Ọni ọdun marundinlọgọta
  • Okonkwo Obiora Francis wa lati ilu Ogidi, nijọba ibilẹ Idemili nipinl Anambra.
  • O jẹ olokoowo nilu Onisha ko to lọ kẹkọ ni fasiti kan lorilẹede Russia.