Sunday Igboho: Gómìnà Akeredolu fi ìdánilójú hàn pé Sunday Ìgbòho Yóò Padà Sílé Láyọ̀ àti Àlááfíà

aworan oluwode kan

Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti fi idaniloju re han pe, ajijangbara fun idasilẹ orilẹ ede Yoruba, Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mọ si sunday Igboho yíò pada si'ile l'ayọ

ati alaafia.

Akeredolu sọ ọrọ yi nigba ti o n ba awọn oluwọde fun itusilẹ Sunday Igboho sọrọ ní ọfiisi rẹ ni ilu Akurẹ.

Gomina ọun ti akọwe ijọba, ọmọbabirin Oladunni Odu ṣoju fun sọpe ọmọ Yoruba rere ni Igboho ti nkankan ko gbọdọ ṣe.

Owa dupẹ lọwọ awọn oluwọde naa fun gbigba alaafia laaye latari iwọde wọn pẹlu idaniloju pe ohun koni di ẹnikẹni lọwọ lati ṣe iwọde ti ko ni jagidijagan ninu.

Siwaju, ọgunlọgọ eniyan labẹ asia ẹgbẹ ọmọ Yoruba ni wọn ti ṣe iwọde ni ilu Akure fún itusile Igboho ti wọn si rin lati agbegbe Old-Garage lọ si ile iṣẹ gomina ti ipinlẹ Ondo.

Awọn oluwọde naa ti ọgbẹni Victor Omojowo gbẹnusọ fun ni wọn rọ Akeredolu ko lo ipo ẹ gẹgẹ bi adari awon gomina ni iwọ oorun Nigeria lati ripe Igboho o ṣe odun keresimesi ni ihamọ ijọba Benin

Republic.O fikun ọrọ rẹ pe nitori alaafia ni awọn duro le lori, awọn agbofinro ko gbọdọ halẹ mọ won.

Awọn to kopa ninu iwode naa ni wọn wa lati ijoba ipinle mejeejidinlogun ti o wa ni ipinle Ondo.

Àkọlé fídíò,

KieKie