Timothy Adegoke: Rahmon Adedoyin ti sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìwádìí òkú ‘autopsy’ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura rẹ̀ nílé Ifẹ̀

Raymond adedoyin ati Timothy adegoke

Oríṣun àwòrán, omoluabitv

Pẹlu bi ọrọ iku Timoth Adegoke ti awọn amokunṣika kan pa si ileetura Hilton Hotel nilu Ile Ifẹ ati iwadii awọn agbofinro lori rẹ ṣe n ja ranyinranyin bayii, ọkan lara awọn afurasi ti wọn mu fun iṣẹlẹ naa, Oloye Ramon Adedoyin to ni ileewe naa ti sọ pe oun ko tii mọ ohunkohun nipa abajade iwadii oku arakunrin to doloogbe naa.

Timoth Adegoke di ologbe lẹyin to lọ wọ si ileetura naa ni igbaradi fun idawo ikẹkọgboye Masters rẹ lọgba fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ University, OAU nilu Ile ifẹ.

Oniruuru iroyin ati gbọyisọyi lo ti n waye lori abajade iwadii oku naa ti olukuluku si n sọ ohun to wo pe o wa ninu rẹ̀.

Amọṣa, agbẹjọro Oloye Ramon Adedoyin, Amofiagba Kunle Ọlagoke, SAN ṣalaye fun BBC News Yoruba pe awọn ko tii ri ẹda iwe iwadii ọku 'Autopsy' naa gba.

"Awa o tii ri eyi ti ijọba fọwọsi to jẹ esi iwadi ohun to lee ṣeku pa oloogbe. A ko tii ri eyi ti ijọba fọwọ si."

O ni eyi ti awọn eeyan n gbe kiri lori ayelujara ti wọn si n sọ oniruuru ọrọ si kii ṣe tootọ rara ṣugbọn o rọ awọn eeyan lati fi ara balẹ ki ijọba ṣe iwadii to tọ lati fi idi otitọ mulẹ.