Bandits kill pastor: Bi agbébọn ṣe pa Pásítọ̀ kan, jí obìrin kan, ọmọ mẹ́rin gbé lọ

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, NPF

Awọn agbebọn ti yinbọn pa pasitọ Dauda Bature to jẹ Alufa ijọ Evangelical Church Winning All (ECWA), ẹka to wa ni agbegbe Narayi, ijọba ibilẹ Chikun ni ipinlẹ Kaduna.

Ohun taa gbọ ni pe awọn ajinigbe kọ́kọ́ ji Bature gbe ko to di pe wọn pa a koda pẹlu bi iroyin ṣe awọn eeyan rẹ san owo itusilẹ ti ẹnikẹni ko mọ iye rẹ fun awọn ajinigbe ọhun lati le tu u silẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa Kaduna ko tii fesi lori iku rẹ, ọkan lara awọn agbaagba ijọ naa fi aridaju iku Alufa naa han si ileeṣẹ Telifisan Channels ni ọjọ Ẹti.

Agba ijọ naa ti ko fẹ ki eeyan darukọ rẹ ṣalaye pe awọn ajinigbe ọhun ji Bature gbe lati ọjọ Kẹjọ oṣu Kọkanla nigba ti o n ṣiṣẹ ni oko rẹ ni agbegbe kan ti wọn ni ko jina si ibudokọ oju irin Rigasa lọna ati jade kuro lagbegbe ilu Kaduna.

Gẹgẹ bi ọmọ ijọ naa ṣe sọ, wọn dede ri oku Pasitọ naa lẹyin ọjọ melo kan ti ẹbi rẹ san owo itusilẹ tawọn ajinigbe bere fun.

Ninu iroyin miran, awọn ajinigbe tun yabo ilu kan nijọba ibilẹ Chikun kan naa ti wọn ti ji Pasitọ yii gbe ti wọn si fi agidi gbe obinrin kan ati ọmọ rẹ mẹrin lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kaduna, Muhammed Jalige to fidi ọrọ naa mulẹ jẹ ko di mimọ ninu atẹjade wọn pe awọn agbebọn ọhun ṣe iṣẹ ibi wọn lasiko kan naa nijọba ibilẹ Sabo GRA nijọba ibilẹ yii kan naa.

"Lowurọ ọjọ Kọkanla oṣu Kejila ọdun 2021 ni nkan bii ago kan oru kọja, ileeṣẹ ọlọpaa Kaduna gbe igbes kanmọ́-kanmọ lori ipe pajawiri ti wọn gba latọdọ ẹlẹyinju aanu kan to ta wọn lolobo pe awọn afurasi agbebọn kan to to ọgbọn tawọn kan si wọ aṣọ bii ologun pẹlu awọn nkan ija to buru jai lọ ja wọ inu ile kan ni Sabo GRA nijọba ibilẹ Chikun.

Àkọlé fídíò,

wọ́n ń fi mi pamọ́ ni lásìkò ti mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága nítorí ọmọdé ni mí

Jalige ni awọn kan sagbami iṣẹ lẹsẹkẹsẹ to si ni bi awọn agbebọn ṣe gburo ọlọpaa wọn bẹtrẹ si ni yinbọn gidi gidi amọ awọn agbofinro tete koju wọn ti wọn si ribi kapaa wọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe nigba ti awọn agbebọn ri ọwọ ti awọn ọlọpaa gbe wa ti wọn o ribi ṣe ohunkohun mọ, ṣe ni wọn dana sun ile ti wọn fẹ kọlu ti wọn si na papa bora.

Amọ awọn ọlọpaa rii gbọ pe awọn agbebọn naa tun n ṣọṣẹ lasiko kan naa ni ilu kan to wa lagbegbe Sabo nibi ti wọ́n ti ji obinrin kan ati ọmọ rẹ mẹrin gbe.

Gẹgẹ bi Jalige ṣe sọ, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ mejeji yii to si ni awọn n ṣe akitiyan lati doola awọn to wa lahamọ ajinigbe.

O fi da awọn araalu loju pe ohun gbogbo to yẹ lawọn ọlọpaa n ṣe lati rii pe alafia to peye pada si agbegbe naa to si ni ki awọn araalu pawọpọ ba awọn ṣiṣẹ.