Sean Imonioro Chukwuemeka: Oyìnbó ẹni ọdún 56 tí mo fẹ́ ní ìhùwàsí gidi ju ọ̀dọ́bìnrin ọmọ Nàìjíríà lọ

"Emi o wo iyatọ to wa ninu ọjọ ori wa, o kan da bii pe ẹgbẹ́ mi ni mo fẹ niyawo ni".
Oju opo Facebook ni Sean Imonioro Chukwuemeka ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to jẹ ọmọ Naijiria ti pade arabinrin ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ti wọn jọ yo ifẹ ara wọn to si di tootọ ti wọn di tọkọ taya.
Agbabọọlu ẹsẹ kuku ni Sean jẹ to n gba bọọlu fun ilu Owerri nipinlẹ Imo bakan naa lo n ṣe iṣẹ afuni lowo latoju ẹrọ ilewọ POS.
O ni lọdun 2020 lawọn mejeji pade loju opo Facebook ibẹ si ni ifẹ ti wọ ọrọ awọn mejeeji titi to fi kọ ẹnu sii pe oun fẹ fi ṣe aya.
Labẹ akọsilẹ "awọn eeyan to ṣeeṣe ki o mọ" eyi ti Facebook maa n gbe jade ni Sean ni oun kan ti ri arabinrin oyinbo naa.
wọ́n ń fi mi pamọ́ ni lásìkò ti mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága nítorí ọmọdé ni mí
"Mo bẹrẹ si ni wo awọn ọrọ nipa oyinbo naa, iru awọn ọrọ to maa n sọ ati oniruuru nkan to maa n fi sita lori itakun rẹ. Mo wa tẹ ami pe mo fran awọn nkan to n kọ mo si kọ ọrọ ranṣẹ sii, bi a ṣe bẹrẹ niyẹn".
Arabinrin naa ti ni ọm mẹta tẹlẹ ki oun ati Sean to fẹ ara wọn amọ o ni oun o ri idaduro ibimọ eyi ti oloyinbo n pe ni menopause bii iṣoro tori awọn eeyan ti n kii nilọ pe obinrin naa lo ni le bimọ fun un.
"Ko sohun to n jẹ menopause niwaju Ọlọrun tori ko si ẹni ti Ọlọrun ko lee fun lọmọnigbakuugba", Sean ni o wa ninu bibeli.
Sean sọ fun BBC pe iyawo oun ti kọkọ ni ọmọ meji to gba tọ latile awọn ọmọ alailobi ko to di pe o bi ọmọ rẹ to ti pe ọmọ ọdun mejidinlogun bayii.
Iyatọ to wa laarin fifẹ arugbo ati ọdọbinrin?
Oríṣun àwòrán, SEAN IMONIORO CHUKWUEMEKA
Gẹgẹ bi Sean Imonioro Chukwuemeka ṣe sọ ọ, iyatọ to wa laarin ki eeyan fẹ ẹni to dagba ju u lọ naa kan ni pe o mọ pe ifọkan tan wa nibẹ, ibọwọ si wa nibẹ".
O fi kun un wipe iyawo oun n tọju oun daadaa amọ eyi ko jọ ọ́ lọ́dọ̀ awọn ọdọbinrin ti yoo maa kùn tabi pariwo le ọ lori too ba ṣẹ wọn.
"O mọ pe o gba ọpọlọpọ ọjọ ori lọwọ mi sibẹ o tun n tọju mi o si n bọwọ fun mi. Ko si ọjọ kan wa ti ko jẹ ki n mọ ala pe oun ni agba ninu ibaṣepọ yii, koda bi iyatọ kọọkan ba wa, yoo fara balẹ ṣalaye fun mi ni".
Sean ni iyawo oun ẹni ọdun mẹrindinlọgọta yii n fun oun ni gbogbo nkan ti oun n reti latọdọ obinrin bii iwa rere ati ihuwasi to dara eyi si ni ala iru iyawo to fẹ.
Oríṣun àwòrán, Sean Imonioro Chukwuemeka
Sean Imonioro Chukwuemeka
Ki ni anfani ti Sean yoo jẹ ninu igbeyawo yii?
O ni oun ko fẹ arabinrin yii nitori ọgbọ awọn anfani oriṣiriṣi ti awọn eeyan ni nkan ti oun n wa niyẹn.
O ni anfani to wa ninu igbeyawo yii fun oun ni idunu ati ayọ pe oun fẹ ẹni to oun ni ifọkanbalẹ ati alafia pẹlu.
"Nigba ti mo kẹnu ifẹ sii, o bi mi pe ṣe ootọ ni gbogbo oun ti mo n ṣe toripe ifẹ mi ti gba ọkan oun so, mo si jẹ ko mọ pe olootọ ni mi".