Soun Ogbomosho: Ka nípa Sòún Ogbomosho to kọ owó #100 mílíọ̀nù tí ìjọba Makinde ní kó fí tún ààfin ṣé

Oríṣun àwòrán, Iwe Ogun Yoruba
Laipẹ yi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin Naijiria kan, Ṣọun Ogbomosho sọ pe itẹlọrun ṣe pataki si ohun gẹgẹ bi ori ade.
Soun ko si lori ilẹ mọ loni ṣugbọn igbe aye Alayeluwa Ọba, Alhaji Dr. Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade III jẹ eleyi ti ọpọ yoo maa ṣe iranti rẹ.
Lowurọ ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ Kejila oṣu Kejila ọdun 2021 ni iroyin gbode pe Soun rebi agba n ree lẹni ọdun marundinlọgọrun.
wọ́n ń fi mi pamọ́ ni lásìkò ti mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alága nítorí ọmọdé ni mí
Nileeṣẹ BBC Yoruba, a gbiyanju lati ṣe agbeyẹwo igbe aye Soun ati awọn nkan tawọn araalu yoo fi maa ranti baba naa.
Ọdun 1926 ni wọn bi Soun si idile Bello Afolabi Oyewumi Ajagungbade II ati Ayaba Seliat Olatundun Oyewumi.
Oke Padre ni St Patrick Primary School ni Soun ti ka ile ẹkọ alakọbẹr laarin ọdun 1932-1938.
Ni 1938 Soun kawe ni Ogbomosho Peoples Institute to ti wa pada wa di Ogbomosho Grammar School.
Soun ko ribi tẹsiwaju nidi ẹkọ rẹ eyi to mu ki o bẹrẹ iṣẹ aṣọ ofi eyi to gbe de awọn ilu bi Ilesa ati ibomiran.
Soun Ogbomoso da ileeṣẹ tirẹ silẹ to pe orukọ rẹ ni J.O Oyewumi and Co ni ọdun 1967.
Ileeṣẹ yi gbooro debi pe Soun pẹka sidi ile tita ati eto inaju to si di gbajugbaja oniṣowo.
Latara bi eledua ṣe bu kun nidi iṣẹ yi, o da ile itura Terminus Hotel ati El-Duniya Hotel silẹ ni Jos.
Ọdun 1973 lo gun ori oye gẹgẹ bi Soun Ogbomoso to si lo ọdun mẹtadinlaadọta lori oye.
Lasiko igbe aye rẹ ọpọ idagbasoke ni Soun mu ba ilu Ogbomoso ti a si maa s pe eto ẹkọ jẹ ohun to jẹ oun logun.
Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀
Laipẹ yi ti awọn kan ṣe ikọlu si aafin Soun lasiko iwọde ENDSARS,awọn eeyan da owo jọ lati ṣe atunṣe aafin koda ijọba Oyo lawọn naa fun Soun lowo fi tun aafin ṣe .
Ohun manigbagbe lo jẹ bi Soun ṣe kọ owo ọgọrun miliọnu Naira yi to si ni ki wọn fi pese iṣ fawọn ọdọ ti ko niṣẹ lọwọ
Oríṣun àwòrán, Premium Times
Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága
Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani