18 year old poisons guardian: Wo bí ọmọ ọdún 18 tó fi májèlé sínú oúnjẹ alágbàtọ́ rẹ̀, ṣe dèrò àtìmọ́lé

Aworan majele ati ọmọbinrin to lo majele

Oríṣun àwòrán, Getty Images, Ogun State Police

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ṣìkún òfin mú ọmọ odún 18 tó gbìyànjú láti fi májèlé pa alágbàtọ́ rẹ̀

Ọmọ ọdun mejidinlogun kan ti ko si gbaga ọlọpaa ipinle Ogun lori ẹsun pe o gbiyaju lati pa alagbatọ rẹ lẹyin to fun ẹni naa ni majele jẹ.

Wọn ni afurasi naa, Tope Fasanya fi majele sinu ounjẹ alagbatọ rẹ, arabinrin Esther Bada.

Awọn ọlọpaa fi ṣikun ofin mu Tope lẹyin ti alagbatọ rẹ fi ọrọ rẹ lọ ni agọ wọn pe inu bẹrẹ si n dun ohun lẹyin ti ounjẹ ti afurasi naa gbe fun oun tan.

O ni lẹyin ti inu bẹrẹ si n dun oun ni oun ke si Tope ko wa tọ ninu ounjẹ naa wo, amọ o kọ jalẹ, eyii to mu ki oun fura pe ọrọ naa kii ṣe oju lasan.

Àkọlé fídíò,

BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Ni kete to fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni wọn gbe obinrin naa lọ sile iwosan gbogbogbo to wa ni Owode Egba, sọgbọn wọn tun tari rẹ lati ibẹ lọ si ile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa ni Abeokuta.

Eyii lo mu ki ikọ akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa fi ṣikun ofin mu afurasi naa to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun.

Nigba to de agọ ọlọpaa, afurasi ọhun kọkọ sẹ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn kan oun.

Ṣugbọn lẹyin ti wọn gbe lọ si ẹka ileeṣẹ naa to n ri ṣe iwadii iwa ọdaran, CID, niluu Abeokuta, o jẹwọ pe lootọ ni oun fi oogun eku sinu ounjẹ alagbatọ oun.

Àkọlé fídíò,

Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn

Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe igba ti afurasi naa wa ni ipele kẹta nile ẹkọ alakọbẹrẹ lo ti wa ni akata alagbatọ rẹ, eyii to jẹ olukọ rẹ lọdun naa lọhun.

Eyii waye lẹyin iku baba afurasi naa, obinrin ọhun lo si n gbọ jijẹ-mimu rẹ lati igba naa wa, to fi mọ ọrọ owo ile ẹkọ rẹ.

Nigba ti awọn ọlọpaa bere eredi ti afurasi naa ṣe gbiyanju lati pa alagabtọ rẹ, o ni ṣe ni oun fẹ pada si ọdọ iya oun, ọna kan ṣoṣo to si wa fun oun ni ki oun mu alagbatọ naa kuro lọna.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ ni kete ti wọn ba ti pari iwadii lori ẹsun ọhun.