Tunde Onakoya Chess in Slums: Ka nípa aláàánú to sọ̀ àwọn ọmọ aláìní 51 di ògbóǹtarìgì aláyò eré Chess

Aworan Fawaz

Oríṣun àwòrán, Tunde Onakoya

Kaakiri loju opo ayelujara ọrukọ arakunrin kan Tunde Onakoya lawọn eeyan n mu bẹnu.

Ko si ṣẹyin bi o ti ṣe seto lati kọ awọn ọmọ alaini kan labẹ afara Oshodi bi wọn yoo ti ṣe maa ṣe iṣiro laiwowe ati tita ere ayo Chess.

Itan taa fẹ sọ yi ko da lori Tunde pupọ bi kii ṣe nipa ọkan awọn ọmọ ti o ko jọ lati kọ nipa Chess ati iru ipa ti igbesẹ yi yooni nigbesi aye wọn.

Ninu awọn ọmọ yi la ti ri Fawaz to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun to gbegba oroke ninu idije ti wọn ṣe fun wọn.

Ṣaaju ki Fawaz to kopa ninu idije yi, iṣẹ kọndọkitọ lo n ṣe ti ko si tiẹ lero pe oun yoo mọ bi wọn ti ṣe n ta ere Chess.

Oríṣun àwòrán, Tunde Awokoya

Ohun ati awọn ọmọ alainilelori mọkanlelaadọta ni wọn ko jọ ti wọn si gba idanilẹkọ nipa tita ere ayo Chess ati ṣiṣe iṣiro lalai wo iwe taa mọ si ''Mental Maths''

Oríṣun àwòrán, Tunde Onakoya

Bi eeyan ba maa n kọja ladugbo Under Bridge ni Oshodi o ṣeeṣe ki o ti ṣalabapade Fawaz ati awọn akẹgbẹ rẹ .

Pupọ ninu wọn ni wn maa n tọrọ owo lọwọ awọn tobaa n kja ti wọn a si maa sun si abẹ afara nitori wọn ko nile lori.

Awọn mii ninu wọn jẹ ọmọ orukan ti igbe aye ko si rọrun fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Tunde Awokoya

Amọ eto ti Tunde Onakoya ṣe jẹ eleyi to loun ro pe yoo mu iyipada ba igbe aye awọn ọmọ wọn yi.

Lara pe ọrọ yoo ri bẹ nipe eeyan kan ti sọpe oun yoo fi ẹrọ kọmputa laptop ta Fawaz lọrẹ ko ba le kọ nipa Coding.

Yatọ si eleyi awọn miran ninu awọn ọmọ yi lo ti ri awọn to jẹjẹ pe awọn yoo ran wọn nileẹkọ.

Oríṣun àwòrán, Tunde Awokoya

Oríṣun àwòrán, Tunde Awokoya

Chessinslums nibo lo ti wọ wa?

Ọsẹ meji gbako ni Tunde Onakoya ati awọn akẹgbẹ rẹ fi lọ kọ awọn ọmọde to wa labẹ afara Oshodi lẹkọ nipa Chess tita.

Igba akọkọ si kọ ni yi ti wọn yoo maa ṣe iru rẹ.

Laipẹ yi ni Tunde gbe ere Chess yi lọ ba awọn ọmọde alaini to wa ni adugbo Makoko nilu Eko ti o si kọ wọn lede Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Tunde Awokoya

Oríṣun àwòrán, Tunde Awokoya

Oríṣun àwòrán, Tunde Onakoya

Lori ohun to jẹ iwuri fun Tunde, O salaye pe idunnu tawọn ọmọ naa maa n fi han lo jẹ idunnu fun oun.

O ni erongba oun ni lati maa ṣe idanilẹkọ ati iwuri fawọn ọmọ wọn yi titi di ọjọ iku.