Imo cannibals arrested: Àwọn jàndùkú ajínigbé tó ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ kó sí gbaga DSS

Awọn to n sun ẹran èèyàn jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eemọ ree o, aye ti fẹlẹ, koda o fẹ le lu jara wọn.

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lo lọ bawọn ajinigbe kan ni buba nibi ti wọn ti n sun ẹran eeyan jẹ bi eranko igbẹ nipinlẹ IMo.

Ọga agba ajọ DSS nipinlẹ Imo, Wilcox Idaminabo sọ fawọn akọroyin pe awọn ẹṣọ DSS ri oriṣiiriṣii oku awọn eeyan ni akata awọn ajinigbe naa.

Àkọlé fídíò,

Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network

Àkọlé fídíò,

Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

Idaminabo ṣalaye pe awọn ẹṣọ DSS ri oniruuru ẹya ara awọn eeyan ti wọn ti pa bi ori to ti n bajẹ atawọn ẹya ara mi ti wọn ti yan bi ẹran igbẹ lakata awọn ajinigbe ọhun.

Idaminabo sọ pe ọgbọn awọn janduku ajinigbe ni ajọ DSS ri mu bo tilẹ jẹ pe wọn doju ija kọ awọn ẹṣọ DSS.

Oríṣun àwòrán, Screenshot of DSS presser

Ọga agba DSS fikun ọrọ rẹ pe iṣẹlẹ yii waye ni ijọba ibilẹ Orsu nipinlẹ Imo ati ijọba ibilẹ Ihiala nipinlẹ Anambra.

O ni lasiko tawọn yabo agọ awọn ajinigbe naa ni awọn doola Eze Acho Ndukwe abule Ihube ti wọn ti jigbe tẹlẹ lọjọ Aiku to lọ.

Àkọlé fídíò,

BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

''Ajọ DSS kọ lo da ṣe aṣeyọri yii, a ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ologun atawọn ọlọpaa ni.

Awọn eeyan agbegbe tawọn janduku ajinigbe yii wa ti sa kuro niluu wọn.

Awọn janduku yii ti n jaye ọlọba lori ilẹ kii ṣe ti wọn, ọrọ wọn dabi awọn agbesunmọmi.

O ya mi lẹnu pe awọn kan si tun n jẹ ẹran eeyan ẹlẹmi bi ti wọn nibi ti aye laju de yii.

Ohun ti wọn n ṣe ni pe, wọn n ji awọn gbe, wọn si n pa ninu wọn,'' Idaminabo lo sọ bẹẹ.