Learn Am App: Kóníléógbélé Covid 19 ló jẹ́ ká ronú gbé 'Learn Am' jáde láti ran àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́- Bola Lawal

Learn Am App: Kóníléógbélé Covid 19 ló jẹ́ ká ronú gbé 'Learn Am' jáde láti ran àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́- Bola Lawal

Ona ti ede Yoruba ko ṣe le parun lo jẹ BBC Yoruba logun.

Eyi lo mu wa gbalejo Arakunrin Bola Lawal to gbe agbelerọ aapu kan to n kọ awọn eeyan ni iṣẹ ọwọ ni ede Yoruba.

Bola Lawal ṣalaye fun BBC pe konile-o-gbele ajakale arun coronavirus to ṣẹlẹ lọdun 2020 lo bi eyi.

O ni Covid 19 lo jẹ ki oun ronu ọna lati wa iṣẹ fun awọn ti wọn ko ni iṣẹ lo jẹ ki oun wa ọna abayọ lati ri owo iranwọ gba lati fi ṣe aapu yii.

Bola Lawal

Bola Lawal Salaye pe gbogbo oniṣẹ ọwọ lo le kọ iru iṣẹ ọwọ to wu wọn ni ede Yoruba, Igbo, Hausa ati Pridin lori Learn Am App yii lọfẹ si ni dátà ti wọn yoo lo lati fi kọ iṣẹ ọwọ naa.

O mẹnuba bi o ṣe ri owo iranlọwọ gba lati ilẹ okeere eyi to lo lati fi ṣe aapu naa ki awọn ọmọ Yoruba le ri ooreọfẹ lati kọ iṣẹ to wu wọn lọfẹẹ nibẹ.

Learn Am

Bola Lawal ṣalaye nipa iṣẹ ọwọ bii mẹkaniiki, ẹni to n tun tẹlifiṣọn ati redio ṣe ati awọn iṣẹ ọwọ miran ti o le ko lori ẹrọ ayelujara ni ọfẹ.

Mọ sii nipa awọn ọmọ Naijiria to n dárà pẹlu owo iranwọ ti wọn ri gba nilẹ okeere fun itẹsiwaju awọn ọmọ Naijiria to ku diẹ kaato fun.