Silas Adekunle: Ó tún sẹ̀sẹ̀ fọwọ́sí àdéhùn alàìmọye mílíọ́nù dọ́là

Silas ADekunle

Oríṣun àwòrán, Forbes

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin ti Adekunle pari eto ẹkọ girama rẹ nilu Eko, lo tẹ ọ̀kọ leti lọ soke okun fun eto ẹkọ fasiti rẹ

Silas Adekunle, tii se ọmọ Yoruba lati ipinlẹ Eko, ni onimọ ẹrọ to n se ‘Ẹrọ-deniyan’, taa mọ si ‘Rọbọti’, to n gba owo to pọ julọ ni ilu ọba.

Iroyin kan fi ye wa pe koda, Adekunle tun ti fọwọsi iwe adehun kan fun sise Rọbọti, eyi ti owo rẹ to aimọye miliọnu dọla.

Koda ikọ kan ti wọn n pe ni Black Hedge Fund Group ti figbe ta pe Adekunle ni ẹni naa ti oju gbogbo yoo maa wo lọdun 2018 lẹka imọ ẹrọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ti Adekunle pari eto ẹkọ girama rẹ nilu Eko, lo tẹ ọ̀kọ leti lọ soke okun fun eto ẹkọ fasiti rẹ, ni University of West England.

Adekunle kẹkọjade nile ẹkọ fasit naa, to si jade pẹlu iwe ẹri isọri akẹkọ kinni to yege, taa mọ si First Class ni ẹka imọ nipa sise ẹrọ deniyan rọbọti, lẹyin eyi lo wa da ileesẹ tara rẹ silẹ, eyi to n se ẹrọ Rọbọti.

Àkọlé fídíò,

OsunDecides: Omisore ní ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò, àwọn yóò lọ lásọ mú ni

Lọdun 2017, nigba to wa nileesẹ MekaMon, ni Adekunle se agbekalẹ Rọbọti akọkọ rẹ eyi tii se Rọbọti akọkọ fun ere idaraya, ti ẹrọ naa si lee sisẹ bii eniyan. Ẹẹdẹgbẹta ẹrọ yii ni awọn eeyan du ra, eyi to pa miliọnu mẹtadinlogun ati aabọ dọla wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Adekunle se agbekalẹ Rọbọti akọkọ rẹ eyi tii se Rọbọti akọkọ fun ere idaraya

Aseyọri yii lo mu ko ri oniruuru atilẹyin gba lati ọdọ awọn ileesẹ nla-nla, to fi mọ ileesẹ London Ventures Patners, ti wọn fun ni miliọnu mẹwa dọla ($10m) lọdun naa. Bakan naa ni ileesẹ rẹ Reach Robots fọwọsi iwe adehun pẹlu ileesẹ Apple lati jẹ ojulowo alagbata fawọn ẹrọ́-deniyan naa.

Àkọlé fídíò,

'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Isẹ ọna to sọnu ni Naijiria di riri loke okun

Ninu Iroyin mi i ẹwẹ, isẹ ona ilẹ Naijiria kan to ti nu tipẹtipẹ lo sadede suyọ ni filati onile kẹjẹbu kan ni ariwa ilu London.

Isẹ ọna naa, to jẹ aworan Ọmọọba Adetutu Ademiluyi lati Ile Ife, eyi ti Ben Enwonwu ya ni odun 1974 di ami isokan orilẹẹde Naijiria leyin ogun abele Biafra.

Àkọlé fídíò,

Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Wọn lero wi pẹ isẹ ọna naa yoo mu ẹgbẹrun lona ọọdunrun poun wa, ti wọn ba lu ni gbanjo.

Eyi yoo jẹ owo to po ju ti ise ona igbalode lati owo omo orilẹẹde yi yoo pa .

Ben Okri, to je akowe ami ẹyẹ Booker ni ''isẹ ọna yi je ọkan gbogi ti wọn se awari rẹ ni bii aadota ọdun sẹyin''

Oríṣun àwòrán, Bonhams

Àkọlé àwòrán,

Won yoo lu awon ise Ben Enwonu ni gbanjo ni Bonhams lojo kejidinlogbon osu keji ọdun 2018

O fi kun pe awari isẹ ọna naa ''pe fun ayo ati idunnu, igba iyipada lo si muba ise ona ''.

Ogbeni Enwonwu, ti opo eeyan ri gẹgẹ bi oludasile ise ọna igbalode lorilẹẹde Naijiria ya orisi meta eda aworan Tutu.

Àkọlé fídíò,

Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Awọn awọran mẹta ohun di awati lẹyin iku rẹ lodun 1994.

Ko si ẹni to mo ibi ti awọn aworan meji toku wa.

Àkọlé fídíò,

Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto